Simon Lalong: Gómìnà ìpínlẹ̀ Plateau ni ẹni tó bá fẹ́ ipò ní ìjọba òun gbọ̀dọ̀ yan ẹranko kan láàyò

Oríṣun àwòrán, Nigeriagalleria.com
Gomina Ipinlẹ Plateau, Simon Lalong ti ni ẹnikẹni to ba fẹ ipo oṣelu labẹ ijọba oun gbọdọ lọ si ọgba ẹranko to wa ni ipinlẹ naa lati yan ẹranko kan laayo, eyi ti yoo maa tọju.
Lalong sọ pe eyi ri bẹ nitori wipe oun ati iyawo oun fẹran ẹranko pupọ, awọn si ti yan awọn ẹranko kan laayo ninu ọgba ẹranko to wa ni ilu Jos lati maa tọju.
O n i iyawo oun yan kiniun meji, ti oun naa si mu erin kan.
Lalong sọrọ kayeefi yii nibi ayẹyẹ ọgọrun ọjọ ti adari ajọ irin ajo afẹ ti ipinlẹ naa, Salome Bidda ti lo lori aleefa.

Oríṣun àwòrán, Nigeriagalleria
Lalong ni igbesẹ naa wa lati fa awọn to n rin irinajo igbafẹ wa si ipinlẹ Plateau.
O ni ti ijọba oun ba ṣe bẹẹ, awọn ẹranko igbẹ to wa ni ọgba naa yoo ni itọju daradara.
Nitori naa, o ni ọkọọkan lara awọn aṣofin mẹrinlelogun to wa ni ipinlẹ naa, ati awọn to jẹ amugbalẹgbẹ oun gbọdọ yan ẹranko ti wọn o maa tọju.
Bẹẹ lo si rọ awọn ara ipinlẹ naa lati ṣe bẹẹ gẹgẹ.
O ni ọkan lara awọn ẹkùn to wa ni ọgba naa ku ni ọdun meji sẹyin. Gomina naa ni ọjọ marun ni oun fi gbaawẹ nigba naa, ti ọfọ si ṣe oun nitori wipe ẹkùn naa n mu owo wa si ipinlẹ naa lọpọlọpọ.
















