Jos crisis: Àwọn òbí n kó ọmọ wọn kúrò ní Unijos

Ami idanimọ̀ Unijos

Oríṣun àwòrán, unijos.edu.ng

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Akẹ́kọ̀ọ́ kan ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀, wọ́n ṣì ń wá ọ̀kan tí àwọn míì sì fara pa nínú rògbòdìyàn tó wáyé ní fásitì ìjọba tó wà ní ìlú Jos.

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti korò ojú sí wàhálà tó wáyé nílùú Jos, olú ìlú ìpínlẹ̀ Plateau.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Buhari sọ pé ''ó n kọmí lómínuu pé àwọn kan ti fàáyè gba iṣẹ́ ibi láti jọba l'ọ́kàn wọn.

Nínú ikèdé kan tí agbẹnusọ fún Ààrẹ Buhari, Garba Sheu fi síta lórí Twitter ni Buhari ti sọ pé òun mọ̀ pé kò rọrùn láti fi ìdí àláàfíà múlẹ̀, ṣùgbọ́n kò yẹ kí àwọn kan tún da omi àláàfíà ti ìjọba ìpínlẹ̀ nàá ti ṣiṣẹ́ fún rú.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Bákan nàá ló sọ pé ẹ̀tọ́ gbogbo ọmọ Nàìjíríà ni ìdàgbàsókè àti ìgbéayé tó f'ẹsẹ̀ múlẹ̀. Ó wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí gbogbo àwọn ìlú tó wà ní olú ìlú ìpínlẹ̀ Plateau, láti gba àláàfíà l'áyè pẹ̀lú àlàyé pé ìbọ̀n tàbí wàhálà kò le yanjú ìkùnsínú kankan, bí kò ṣe títẹ̀lé òfin.

Ní ìtẹ̀síwájú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ààrẹ Buhari ní o ṣeni láànú pé àwọn olóṣèlú kan n gbé ẹlẹ́yàmẹ̀yà àti ọ̀tẹ̀ ẹ̀sìn l'árugẹ fún òkìkí ara wọn.

O ní ìṣàkóso òun yóò tẹ̀síwájú láti maa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn láti le wá àtúnṣe sí orísun rògbòdìyàn tó n wáyé ní gbogbo ìgbà ní ìpínlẹ̀ Plateau àti àwọn ìbòmìí tí wàhálà ti n wáyé ní Nàìjíríà.

Inú àìbalẹ̀ ọkàn ni àwọn tó n gbé ní agbègbè fásitì ilú Jos, nípìnlẹ̀ Plateau wà.

Ní ọjọ́ àìkú tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀, ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì ọ̀hún sọ fún BBC pé àwọn ṣì n gbọ́ ìró ìbọn kíkan-kíkan ní ìwájú ẹnu ọ̀nà tó wọ iléèwè nàá, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbí sì ti n yawọ ọgbà iléèwé láti mú ọmọ wọn.

Unijos

Oríṣun àwòrán, Unijos

Àkọlé àwòrán, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbí sì ti n yawọ ọgbà iléèwé láti mú ọmọ wọn lọ sílé.

Akẹ́kọ̀ọ́ nàá sọ pé l'ọ́jọ́ Àìkú ni àwọn kan tó wọ aṣọ ológun wọ inú ọgbà iléèwé ọ̀hún, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yìnbọn mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́, èyí tó padà yọ́rí sí ikú akẹ́kọ̀ọ́ kan tó wà ní ìpele kẹta.

Àkọlé fídíò, NLC: Àwọn olósèlú ń la títì láì sanwó osù torí owó tí wọn yóò rí lórí àkànse isẹ́

Akẹ́kọ̀ọ́ nàá tó ní kí BBC fi orúkọ bo òun ní àṣírí sọ pé àwọn aláṣẹ fásitì nàá kò tí pàṣẹ́ kankan fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ nàá, ṣùgbọ́n àwọn tó kù síléèwè farapamọ́ sí ilégbèé wọn.

Ìṣẹ̀lẹ̀ nàá ti mú kí ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà maa késí ìjọba àti àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò lórí ẹ̀rọ ayélujára láti tètè dásí ọ̀rọ̀ nàá.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Skip X post, 4

End of X post, 4

Nígbà tí BBC kàn sí alukoro iléèṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Plateau, Terna Tyopev, lórí ọ̀rọ̀ nàá, ó sọ pé òun kò ní ohunkóhun láti sọ lórí rẹ.

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí rògbòdìyàn yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ Plateau, nítorí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibi tí wàhálà ti n wáyé láàrin àwọn àgbẹ̀ àti daran-daran ní Nàìjíríà.

Wàhálà yìí pọ̀ débi pé Gómìnà ìpínlẹ̀ nàá, Samuel Lalong, p'àṣẹ kónílé ó gbélé láti ìrọ̀lẹ́ di òwúrọ̀ l'ọ́jọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn án, ní olú ìlú ìpínlẹ̀ nàá, Jos, lẹ́yìn tí rògbòdìyàn kan mú ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lọ.