Òkè Ìdànrè: Òkè tó kéré jùlọ jẹ́ ẹsẹ̀ bàtà 3000

Àkọlé fídíò, Òkè Ìdànrè: Òkè tó kéré jùlọ jẹ́ ẹsẹ̀ bàtà 3000

BBC Yoruba rin irinajo lọ silu Idanre nipinlẹ Ondo, niti ti Oke Idanre wa lati mọ nipa ohun to se ara ọtọ nipa ori oke yii.

Gẹgẹ bii Atọnisọna lori oke naa, Gbenga Oyinbo ti wi, ibudo isinmi bii ogun lo wa lori oke yii, fawọn eeyan to n rin irinajo afẹ lati sinmi.

Lara rẹ si ni ibudo isinmi Ọwá ati Dágunró wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oyinbo s fun wa pe oke to kere ju lori Oke Idanre lo jẹm ẹgbẹ́run mẹta ẹsẹ bata nigbati eyi to ga julọ nibẹ jẹ ẹ́gbẹrun mẹfa.

BBC Yoruba tun foju ganni ileẹ́kọ alakọbẹrẹ akọkọ nilu naa ti wọn kọ lọdun 1896, ile ijọsin ọmọlẹyin Kristi kinni, aafin ọba akọkọ atawọn ile alarabara ti wọn ti kọ laye atijọ, amọ to si duro di oni.