Buhari fún Ẹ̀ka ìdájọ́, ilé àsòfin ìpínlẹ̀ l'òmìnira owóòná

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Buhari/ Twitter

Àkọlé àwòrán, Ààrẹ Muhammadu Buhari tí fún ilé-iṣẹ́ adájọ ìpinlẹ̀ àtí àwọn ilé ìgbìmọ aṣofin ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni òmìnira owóòná,

Ààrẹ Buhari tí f'ofin de igbákejì gómìnà àti ti àarẹ láti lo sáà meji gẹ́gẹ́ bii olórí tuntun

Aarẹ buwọ́lu abadofin mẹrin, ọ̀kan níbẹ̀ ní o ti fún ilé-iṣẹ́ adájọ ìpinlẹ̀ àtí àwọn ilé ìgbìmọ aṣofin ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni òmìnira owóòná.

Èyí jẹ́ àbájáde àtúnṣe òfin tí ilé ìgbìmọ̀ asojú-sofin gùnlé, láti ṣẹ àtúnṣe sí àwọn òfin kan nínú ìwé òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tọdún 1999.

Bákan náà, ààrẹ tún buwọ́lu àbádòfin mẹ́rin gẹ́gẹ́ bíi àtúnṣe iwé òfin ọdún 1999.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọ̀kan nínú àwọn òfin ọ̀hún tún ni fífún àjọ eletò ìdìbò (INEC) ní àsìkò tó péye láti se àtúndì ìbò.

Kò tán síbẹ̀, lára òfin náà ló tún ní, igbákejì ààrẹ tó bá parí sáà pẹ̀lú ọ̀gá rẹ̀, tó tún fẹ́ lọ se ààrẹ, yóò lo sáà kan soso péré.

Bákan náà ni òfin yìí tún kan àwọn ìgbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ tó bá parí sáà pẹ̀lú ọ̀gá rẹ̀.

Olùrànlọ́wọ́ fún ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ ilé asòfin àgbà, Ita Enang, ló sísọ̀ lójú ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn akọ̀ròyìn ní ilé ìjọba ní Àbújá.

Àkọlé fídíò, Fídíò BBC yọ àwọn èèyàn FIFA níṣẹ́ ṣááju Russia 2018