Iṣẹ́ ti ń lọ lọ́wọ́ láti dóòlà ọgbọ̀n èèyàn tó há sábẹ́ ibùdó ìwakùsà tó dàwó ní ìpínlẹ̀ Niger

Oríṣun àwòrán, getty images
Ọpọ awọ awakusa lo ti ri lẹyin ti koto ti wọn ti n wa kusa wo le wọn lori nipinlẹ Niger.
Ọjọ Aje ni iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti ojo rọ lagbegbe naa amọ ọpọ eeyan ni ko gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun latari iyanṣelodi ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, NLC ati TUC.
Abẹnusọ ileeṣẹ to n ri si ọrọ pajawiri ni nipinlẹ Niger, Hussaini Ibrahim sọ fun BBC pe eeyan kan ti jade laye, nigba ti awọn eeyan ọgbọn mii ṣi wa labẹ ilẹ to wo le wọn lori, amọ akitiyan n lọ lọwọ lati doola wọn.
Awọn alaṣẹ ni awọn gbagbọ pe ojo to rọ laagbege ti wọn ti n wakusa lo ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun.
Hussaini Ibrahim sọ pe “laarọ oni Ọjọru, a gbagbọ pe o le ni ọgbọn eeyan to ṣi wa labẹ ilẹ to wo le wọn lori, a ko tii le fun yin ni iye eeyan to ri sibẹ pato bayii, awọn to n ṣiṣẹ niobẹ gan ko le sọ.
“A le fidi rẹ mulẹ pe a ti yọ ẹnikan ti jade laaye, a si ti doola awọn mẹfa ta a ti gbe lọ sile iwosan.
O fi kun pe ọkọ nla to maa n wu ilẹ ti wa nibẹ lati yọ awọn eeyan ọhun.
Minista fun ohun alumọni, Dele Alake ni awọn oṣiṣẹ to n ri si ohun alumọni ni Naijiria ti lọ sibẹ.
Alake sọ pe “A fẹ ki ẹ mọ pe a maa ṣe iwadii iṣẹlẹ laabi naa lọna ati dena iru rẹ lọjọ iwaju.
Wayi o, ipinlẹ Niger wa lara awọn ipinlẹ ti ajinigbe ti n ṣọṣe julọ ni Naijiria.
Lọdun to kọja, ijọba ipinlẹ naa fofin de iwakusa lagbegbe Shiroro lẹyin ti ilẹ wo pa awọn kan to n wakusa nibẹ.















