Kí ló ṣẹlẹ̀ láàrin àgbà òṣèré, Lawori, tó ṣe ń pariwo pé Koko Zaria fi ìgò fọ́ òun lórí?

Lawori, Koko Zaria

Oríṣun àwòrán, The News Chronicle

Lati bi ọjọ diẹ sẹyin ni ẹnu ti n kun gbajugbaja ọmọ ẹgbẹ awakọ eero, NURTW, ẹka tipinlẹ Eko, Koko Zaria, fun bi oṣerekunrin, Ibrahim Bello Sanya, Lawori, ṣe fi ẹsun ifiya jẹni kan an.

Ṣaaju ni ti ọpọ mọ si Lawori, ninu fidio kan to fi sita lori ayelujara, fi ẹsun kan Koko Zaria pe, oun lo ni ki wọn o fọ igo mọ ori oun.

Ninu fidio ọhun bakan naa, lo ti ṣafihan ori rẹ ti wọn lẹ 'plaster' mọ.

Iṣẹlẹ naa ni Lawori ṣalaye pe o waye ni ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2024, nibi ayẹyẹ Idimu Day 2024.

"Ọmọ Naijiria, ẹ dide iranlọwọ fun mi, ki n ma ba jẹ iya ajẹgbe"

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Lawori ni, nibi ti oun ti n ṣe iṣẹ oun gẹgẹ bii oludari ayẹyẹ, ti wọn n pe ni MC, loju agbo ọhun ni ọkunrin kan ti oun ko mọ, ti wa sọ fun oun pe Koko Zaria n pe oun.

"Kiakia ni mo sọ kalẹ lori itage, ti mo si lọ da a lohun.

" Bi mo ṣe lọ ba Koko Zaria lati ki, o beere pe ṣe mi o ri awọn nibi ti awọn joko si ni. Mo si bẹẹ pe ko ma binu, pe maa ṣatunṣe ti mo pada sori itage."

Lawori sọ pe nibi ti awọn ti n sọrọ, ni oun ti gbọ ti ẹnikan n beere pe ṣe oun ni wọn n pe ni Lawori.

" Gbogbo ero ọkan mi ni pe ẹni naa ko mọ mi, to si n ri mi fun igba akọkọ. Awọn to wa nibẹ sọ fun pe emi ni.

"Bi mo ṣe boju wẹyin, ni mo ri ọkùnrin naa to mu igo ọti kan niwaju Koko Zaria ati awọn ti wọn jọ jokoo, to si fọ ọ mọ mi lori."

Oṣerekunrin naa fikun ọrọ rẹ pe, ni ṣe ni gbogbo ara oun kun fun ẹjẹ, ti oun si daku.

"Mi o mọ bi mo ṣe de ileewosan. Mo kan ṣaa mọ pe, wọn ran ori mi."

Ọgbẹ ọhun ni Lawori sọ pe o n fun oun ni irora pupọ, ti oun kii si ri oorun sun.

Nitori naa si lo ni oun ṣe n bẹ awọn ọmọ Naijiria, lati dide iranlọwọ fun oun, ki oun ma ba jẹ iya ajẹgbe.

Koko Zaria sọrọ lori ẹsun ti Lawori fi kan an

Ninu fidio kan to fi si ori ayelujara Instagram rẹ lọjọ Aje, ọjọ Kini, oṣu Keje, lo ti sọ pe oun ko mọ nipa ikọlu naa.

Koko Zaria ṣalaye pe loootọ ni oun lọ sibi ayẹyẹ naa, amọ oun ko fun ẹnikẹni ni aṣẹ lati kọlu oṣerekunrin naa.

"Lawori ko ṣẹ mi ri, a si sunmọ ara wa daadaa."

"Mo pe Lawori ki n le ki, ki n si le tọrọ aforijin fun bi mo ṣe kuna lati yọju sibi iṣẹ kan to pe mi si.

" Igba to pada sori itage, mo ri pe awọn ọkunrin meji n ba a ja nitori pe o da orin ti wọn n gbọ duro."

Koko Zaria sọ pe oun ni oun gbe Lawori lọ sileewosan, ti oun si sanwo itọju rẹ.

"Mo duro tii nileewosan, ki n to pada sile ni bi aago kan oru."

O ni koda, Lawori pe oun ki lọjọ keji lati dupẹ.

"Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe o tun n fi ẹsun kan mi.

Agbẹnusọ ileeọ̀ẹ ọlọpaa sọrọ nipa isẹlẹ naa

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Ọgbẹni Muyiwa Adejobi sọ pe iwadii yoo waye lori ọrọ naa. Ati pe idajọ ododo yoo waye.

O sọ eyi lori ayelujara X rẹ, nigba ti awọn eeyan kan pe akiyesi rẹ si fidio ti Lawori fi sita.

Ọrọ ti ileeṣẹ ọlọpaa sọ

Oríṣun àwòrán, Muyiwa Adejobi/Screenshot/X

Taa ni Koko Zaria?

Ganiyu Ayinde Oyedepo ni orukọ abisọ rẹ, ṣugbọn Koko Zaria, ni ọpọ mọọ si.

Wọn bi Ọgbẹni Oyedepo lọdun 1970.

O si jẹ eekan pataki ninu ẹgbẹ awakọ ero, NURTW, nipinlẹ Eko.

Yatọ si eyi, Koko Zaria tun jẹ oṣere Nollywood Yoruba.

Lara awọn sinima to ti ṣe ni Atunida, Ryan Re, Kesari, ati Omo Oshodi.

Awọn iroyin kan sọ pe ibatan ni Koko Zaria jẹ si agba iranṣẹ Ọlọrun, Biṣọọbu David Oyedepo.