Ajínigbé yìnbọn fún awakọ̀ àdáni méjì, wọ́n jí awakọ̀ kan gbé lọ, ba mọ́tò méjì jẹ́ lọ́nà márosẹ̀ Ṣagamu si Ijẹbu-Ode

N ṣe lọrọ di bi o ko le lọ, ki o yago lọna nigba ti awọn agbebọn kan, tẹnikẹni ko tii mọ titi di asiko yii, ji arinrinajo kan gbe salọ lalẹ ọjọ Aiku ana.
Opopona marosẹ Ṣagamu si Ijẹbu-Ode ni wọn ti ji awakọ naa gbe ni nnkan bi agogo mẹjọ alẹ, lagbegbe ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun Ṣagamu ati ilu Illiṣan.
Ọkunrin naa, to n rin irin ajo ni wọn sọ pe awọn agbebọn ọhun tẹle lẹyin, ti wọn si sẹburu rẹ nibi ti oju ọna naa ti bajẹ, ko to di pe wọn dabọn bo taya mọto rẹ lati ri aaye ji gbe salọ.
A gbọ pe awọn agbebọn yii tun yinbọn fun awakọ miran to kagbako lọwọ wọn lẹsẹ, ti awọn miran si farapa yannayanna.
Ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ ni ọkan lara awọn ero to fara kaaṣa iṣẹlẹ ọhun, lo ti n gba itọju ni ile iwosan olukọni ti Babcock.
O ni ẹsẹ ni wọn ti yinbọn fun ọkunrin naa lasiko to n gbiyanju lati sa asala fun ẹmi rẹ, ṣugbọn to sọ pe niṣe lawọn agbebọn sa wọnu igbo lọ.
Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni awọn ajinigbe ji awọn meji kan gbe, ti wọn si tun pa ọkan lara awọn ọjọgbọn ni fasiti Babcock ni gbọngan ayẹyẹ tu Ajadeh to wa loju ọna Ipẹru si Ṣagamu, Ipẹru Rẹmọ.

Oríṣun àwòrán, Omolola Odutola/Facebook
Ko si ẹni to ku ninu isẹlẹ naa, ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ iwadii - Agbẹnusọ
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ laarọ ọjọ Aje, SP Ọmọlọla Odutọla to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Ogun sọ pe awọn ti bẹrẹ sii tọpinpin awọn ajinigbe naa, to si ni igbagbọ wa pe ọwọ yoo tẹ wọn.
Odutọla ninu atẹjade naa ṣalaye pe, ọkunrin kan ni awọn ajinigbe ọhun tọpinpin rẹ de agbegbe ti ọna ko ti dara lopopona marosẹ ọhun, ko to di pe yinbọn ba taya mejeeji to wa ni ẹyin ẹsẹ mọto rẹ lati le daa duro.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Ikọ ẹgbẹ agbebọn kan ti a ko le sọ pato iye wọn, ninu mọto Toyota Venza ti ko ni nọmba idanimọ, ni wọn tọpinpin ọkunrin kan to wa ninu Toyota RAV4, alawọ eeru rẹ pẹlu nọmba idanimọ AGL-16-JE.
“Bi wọn ṣe de agbegbe ti ọna ko ti dara, ni wọn wa mọto dina mọ mọto ọkunrin naa.
“Awọn ọdaran naa yinbọn ẹlẹnu mẹrin ti igbagbọ wa pe AK-47 ni wọn gbe dani yinbọn fun taya ẹyin rẹ, ti wọn si tun yinbọn fun taya iwaju.
Loju ẹsẹ ni wọn bọ silẹ, ti wọn si wọ ọkunrin ọhun bọ silẹ lati wọ inu mọto rẹ, ko to di pe wọn mori le ọna Ijẹbu-Ode.
“Lasiko ikọlu naa, awọn ọdaran yii tun yinbọn fun awakọ Toyota Camry, alawọ dudu kan lẹsẹ lasiko to n gbiyanju lati yipada, ko si salọ.
Bakan naa ni wọn tun fọ gilaasi awakọ bọọsi kan to n rin irin ajo lati Abuja si Eko, ti wọn si gba foonu rẹ lọ, pẹlu ikilọ pe oun kọ ni wọn n wa.”
Odutọla fidi rẹ mulẹ pe, ko si ẹni to padanu ẹmi rẹ ninu ikọlu ọhun, ati pe, awọn mọto meji to bajẹ ninu ikọlu naa ni wọn ti wọ lọ sagọ ọlọpaa to wa nitosi.
O fi kun ọrọ rẹ pe ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti gbọ si iṣẹlẹ naa, to si ti paṣẹ pe ki ikọ to n ri sọrọ ijinigbe bẹrẹ iṣẹ iwadii lẹkunrẹrẹ.















