Ààrùn kọ́lẹ́rà ti rá pálá wọ ọgbà ẹ̀wọ̀n Kiríkirì - NCDC

Ọgba ẹwọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kọmiṣanna fọrọ eto ilera nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayomi ti kede pe awọn ti kofiri awọn aisan kan to jẹ mọ ti ajakalẹ arun onigbameji ti a mọ si Kọlẹra ninu ọgba ẹwọn Kirikiri to wa nipinlẹ Eko.

Ọjọgbọn Abayọmi lo sọ eyi lati tako ọrọ ti awọn alakoso ọgba ẹwọn sọ laipẹ yii wi pe gbogbo ọgba ẹwọn ni awọn ti ṣabojuto rẹ lati dena arun ọhun.

Bi ẹ ko gbagbe, l’Ọjọru ọsẹ to kọja yii ni ileeṣẹ to n ri sọrọ ọgba ẹwọn ni Naijiria, NCS jẹ ko di mimọ pe, ko si eyikeyi ọgba ẹwọn to wa lorileede yii to le e ni arun kọlẹra.

Abubakar Umar to ba akọroyin sọrọ ṣalaye pe, itọju ti awọn n ṣe ni gbogbo igba ti ṣe iranwọ lati ma le jẹ ki arun ọhun wọ ọgba ẹwọn kaakiri.

"Eeyan marundinlọgbọn lo lugbadi arun kọlẹra ninu ọgba ẹwọn kirikiri"

Ṣugbọn ṣa, ninu atẹjade ti alakoso fọrọ to nii ṣe pẹlu araalu nileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Eko, Tunbosun Ogunbanwo gbe sita ni awọn ti kofiri arun kan to pe ni gastroenteritis, to jade lati ara arun kọlẹra.

Ogunbanwo sọ pe awọn ti bẹrẹ eto ilera pajawiri lati rii pe ohun gbogbo pada bọ sipo.

Ṣugbọn ṣa, ajọ to n gbogun ti itankalẹ aisan ati ajakalẹ arun lorileede Naijiria, NCDC ti ṣe akọsilẹ eeyan mejidinlọgọfa to ti lugbadi arun kọlẹra nipinlẹ Katsina.

Lara awọn ipinlẹ ti arun naa tun ti n ṣọṣẹ ni Bayelsa, Zamfara, Abia, Cross River, Bauchi, Delta, Katsina, Imo Nasarawa ati Eko.