Ẹgbẹ́ òṣèlú Ààrẹ Macron lulẹ̀ nínú èsì ìdìbò ilé aṣòfin ilẹ̀ France tó tíì jáde

Aworan awọn eeyan France

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ oṣelu far-right National Rally (RN) lo ṣi n lewaju ninu eto idibo orilẹede France.

Ẹgbẹ oṣelu naa lo jawe olubori julọ ninu ipele kinni eto ibo ile aṣofin to waye lana ọjọ Aiku.

Niṣe lawọn ọmọlẹyin ọkan lara awọn adari ẹgbẹ RN to faramọ eto adari ẹgbẹ naa, Marine Le Pen’s, to tako eto Aarẹ Emmanuel Macron lori lilọ bibọ awọn eeyan si orilẹede France n dunnu lẹyin ti esi ibo naa jade.

Ẹgbẹ oṣelu RN ni ibo ida 33.1% nigba ti ẹgbẹ oṣelu left-wing alliance ni 28%, ti ẹgbẹ Aarẹ Macron ṣi ni ibo ida 20.76%.

Jordan Bardella ọmọ ọdun mejildinlọgbọn to jẹ adari ẹgbẹ RN sọ pe ‘’afojusun mi ni lati di olootu ijọba orilẹede France tawọn araalu ba dibo fun wa daadaa.’’

Ko tii ṣẹlẹ ri pe ẹgbẹ oṣelu RN jawe olubori ninu ipele akọkọ eto idibo ile aṣofin orilẹede France.

Onwoye nipa eto oṣelu, Alain Duhamel, sọ pe o ti wọ inu iwe itan bayii pe igba akọkọ ree ti ẹgbẹ RN yoo ṣe iru aṣeyọri bayii ninu eto idibo France.

Ijokoo 289 ninu 577 to wa nile aṣofin orilẹede France ni Le Pen ati Bardella n wa lati di ẹgbẹ oṣelu to ni aṣoju to pọ julọ nile aṣofin.

Amọ, iwoye awọn onimọ nipa eto oṣelu n ti fihan pe ẹgbẹ RN le ma rọwọ yọ ninu abala keji eto idibo ile aṣofin ti yoo waye lọjọ Aiku to n bọ.

Lẹyin ipele akọkọ eto idibo ile aṣofin, ẹgbẹ oṣelu RN ti ni aṣofin mẹtadinlogoji to wọle ibo, nigba ti ẹgbẹ left-wing ni mejilelọgbọn.

Ọpọlọpọ ọmọ ẹgbẹ left-wing lo fi aidunnu wọn lori bi ẹgbẹ RN ṣe lewaju ninu ipele kinni ibo aṣofin orilẹede France.

Aarẹ Macron ko sọrọ lori esi idibo ipele akọkọ ile aṣofin, olootu ijọba, Gabriel Attal, lo sọ pe asiko ti to fawọn oloṣelu lati ṣiṣẹ papọ ninu ipele keji ibo ile aṣofin to n bọ.

Olootu ijọba Attal ni ẹgbẹ oṣelu RN ko gbọdọ ri ibo kankan ninu abala keji eto idibo ile aṣofin to n bọ.

O fikun ọrọ rẹ pe ẹgbẹ RN ko gbọdọ ni ọmọ ẹgbẹ to pọ julọ nile aṣofin.

Ẹwẹ, Jean-Luc Mélenchon, to jẹ olori ẹgbẹ oṣelu France Unbowed (LFI), ti sọ pe o da oun loju pe Ọgbẹni Attal yoo padanu ipo rẹ gẹgẹ ni olootu ijọba orilẹede France.