Ẹ̀mí méjì ṣòfò, ọ̀pọ̀ dúkìá bàjẹ́ lásìkò ìwọ́de àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ Sumal n‘Ibadan

Awọn oṣiṣẹ Sumal, ileeṣẹ nla ti wọn ti n peelo oriṣiriṣi nnkan ipapanu ati ọkanojọkan ounjẹ niluu Ibadan, ṣe ifẹhonuhan lọjọ Aje lati pe fun alekun owo oṣu ati nnkan amayedẹrun nitori ipenija ọrọ aje to n ba Naijiria finra.
Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ nibi ifẹhonuhan naa, tí ọpọ dukia si bajẹ, ti ẹmi meji si ṣofo nibẹ.
BBC Yoruba ṣe abẹwo si ileeṣẹ naa l'owurọ oni ọjọ Iṣẹgun lati wo ibi ti nnkan ṣe de duro.
Ọkan lara awọn olufẹhonuhan naa, ti ko fẹ ki a da orukọ oun ṣe alaye fun akọroyin wa pe, ileeṣẹ naa ke si awọn ọlọpaa lasiko ti ifẹhonuhan n lọwọ.
"Awọn oluwọde ya bo ọlọpaa to wa doola ija, wọn lù ú ni alubami, tawọn ọlọpaa si pa meji lara awọn osisẹ to n sewọde naa"
O tẹsiwaju pe ninu igbiyanju lati pana awuyewuye naa ni awọn to n fi ẹhonu han ti yabo ọlọpaa kan, ti wọn si lu u ni alubami.
O ni iṣẹlẹ yii lo mu ki ọlọpaa kan yinbọn, ti o si gba ẹmi okere tan, meji lara awọn olufẹhonuhan naa.
Iroyin ti o to wa leti ni pe awọn oṣiṣẹ naa gbe oku awọn akẹgbẹ wọn lọ si olu ileeṣẹ Sumal to n bẹ ni agbegbe Oluyole niluu Ibadan, ki o to di pe wọn ti ibẹ gbe wọn lọ si mọṣuari.
Ọpọlọpọ awọn eeyan to n kọja lọ jẹjẹ laisiko naa ni awọn olufẹhonuhan naa lu ti wọn si tun ba gilaasi ọkọ wọn jẹ.
Lẹyin eyi ni wọn tun bẹrẹ si ni pin awọn ipapanu ti ileeṣẹ naa n pese fun awọn eeyan to kọja lọ lọfẹẹ.

Ọdọọdun ni irufẹ ifẹhonuhan yii maa n waye ni ileeṣẹ Sumal
Titi di owurọ oni ni awọn ọlọpaa duro wamuwamu si ayika ileeṣẹ naa ti wọn si n mojutọ lilọbibọ ọkọ ati awọn eeyan to n fi ẹsẹ rin lọ ni agbegbe naa.
A kan si ile ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ naa to n bẹ ni ayika ileeṣẹ nla naa lati ba awọn alakoso sọrọ, ṣugbọn ilẹkun ile ẹgbẹ naa wa ni titi pa.
Bakan naa si ni a gbiyanju lati ba awọn alakoso ileeṣẹ naa sọrọ ṣugbọn awọn agbofinro ko fi aye naa silẹ.
Igbiyanju wa lati ba ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ sọrọ lori iṣẹlẹ naa ja si pabo lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.
Ohun ti a le fi idi rẹ mulẹ ni wi pe ọdọọdun ni irufẹ ifẹhonuhan yii maa n waye ni ileeṣẹ naa.
Aleekun owo oṣu ati ipese awọn ohun amayedẹrun naa si ni awọn oṣiṣẹ naa maa n pe fun ni gbogbo igba.
















