Makinde, àgbá ẹ̀tù ní ètò ààbò wà l‘Oyo tí o kò bá yanjú aáwọ̀ ẹ̀sìn tó ń wáyé ní Iseyin àti Ogbomoso - Ẹgbẹ́ Mùsùlùmí

Aworan

Oríṣun àwòrán, COLLAGE

Ẹgbẹ awọn ẹlẹsin Musulumi nipinlẹ Ọyọ labẹ aburada MUSCOYS ti rawọ ẹbẹ si Gomina Seyi Makinde lati tete dide yanju awọn wahala to n ṣẹlẹ niluu Ogbomọṣọ, ko di pe o fẹju kọja sisọ.

MUSCOYS lo pe ipe yii ninu atẹjade ti alaga wọn, Alaaji Kunle Sanni ati akọwe wọn Alaaji Murisiku Siyanbade buwọ lu lọjọ Iṣẹgun to kọja yii.

Lori ọrọ aawọ to n ṣẹlẹ laarin Ṣọun ati Imaamu tiluu Ogbomọṣọ pẹlu ti Pasitọ Damilola Stephen, to lu Sheikh Sulaiman fọ lori niluu Isẹyin, ni ẹgbẹ MUSCOYS n rawọ ẹbẹ fun.

Wọn ni bi Gomina Makinde ko ba tete dide s’awọn ohun to n ṣẹlẹ yii, o ṣee ṣe ki ọrọ naa doju eto aabo ipinlẹ Ọyọ bọlẹ lojiji.

Bakan naa ni wọn ni ki Makinde pe gbogbo awọn ti ọrọ kan lati jokoo papọ, ki wọn si ba wọn pari ohunkohun to le maa fa wahala laarin wọn, lati le gba alaafia laaye laarin ilu.

Bẹẹ ni wọn sọ pe awọn fẹ kibibọn la jokoo le.

“Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde, gẹgẹ olori eleto aabo ipinlẹ yii ni lati dide, ko si gbe igbesẹ to yẹ lati rii pe oun pana awọn wahala naa, ko to di pe o dabaru eto aabo.

"A ti pe ipade lọpọ igba lati yanju aawọ naa amọ igun mejeeji to n taporogan fariga"

Atẹjade naa salaye pe “lori wahala Imaamu Ogbomọṣọ, bo tilẹ jẹ pe ọrọ ẹbi Ayilara ni tẹlẹ, ṣugbọn o ti wa dide, to si ti di ti Ṣọun Ogbomọṣọ ati kọja ilu Ogbomọṣọ funra ẹ.

“Ẹgbẹ Musulumi l’Ọyọ ti gbe oriṣiriṣi igbesẹ lati yanju aawọ naa, ṣugbọn to pada ja si pabo.

Koda, awọn igbimọ agbaagba ninu ẹgbẹ Musulumi yii, ti Ọjọgbọn D.O.S Noibi jẹ adari rẹ, ti dide lọpọ igba lati ba awọn tọrọ kan sọrọ, ki wọn si jawọ.

“Ipade ti wọn ṣe gbẹyin, awọn ti inu n bi yii mu igbimọ agbaagba ti Ọjọgbọn Noibi lọ siluu Ogbomọṣọ.

“Laipẹ yii ni Aarẹ Musulumi nilẹ Yoruba, Edo ati Delta, Alaaji Dawud Makanjuola Akinola naa tun pe awọn agbaagba Musulumi jọ, ti wọn si tun ṣepade papọ pẹlu awọn igun mejeeji ti inu n bi yii.

“Awọn igbesẹ wọnyi lo jẹ pe eso rere diẹ lo so.

Awọn ọdọ Ogbomọṣọ ti wọn wa lẹyin Imaamu lawọn ko ni wọn-ọn kun, awọn igun keji naa sọ pe awọn ko ni gba a laabọ."

Atẹjade ti ẹgbẹ MUSCOYS fi sita

Oríṣun àwòrán, MUSCOYS/Release

"Iwe ẹsun ti wọn kọ ranṣẹ si Imaamu Yunus Ayilara lasiko to wa nilẹ mimọ Hajj, tun fẹ aawọ naa loju kẹkẹ"

Atẹjade ti ẹgbẹ MUSCOYS fi sita tẹsiwaju pe “Iwe ẹsun ti wọn kọ ranṣẹ si Imaamu, Sheikh Taliat Yunus Ayilara lasiko to wa nilẹ mimọ Hajj, nibi to ti ṣẹṣẹ de, tun jẹ eyi to tun fẹ ọrọ naa loju kẹkẹ.

“Gbogbo igbiyanju awọn alabasọrọ lo ja si pabo, nitori pe ko si ẹnikẹni to lagbara ninu awọn to fẹ yanju aawọ naa.

Ijọba nikan lo le gbe aṣẹ dide, ki wọn si da are fun alara, ati ẹbi fun ẹlẹbi.

“Gẹgẹ bi a ti ṣe mọ pe ojuṣe ijọba ni lati daabo bo ẹmi ati dukia aralu.

Atunṣe ati ibaṣepọ pajawiri to dan mọnran lohun ti n fẹ lasiko yii.

“A wa n pe ọlọlajulọ, Gomina ipinlẹ Ọyọ lati ranṣẹ pe gbogbo awọn ti ọrọ yii kan, ki wọn si ba wọn sọrọ lati yanju aawọ to n da wahala silẹ, ki wọn si tun gbe aṣẹ kalẹ fun onikaluku wọn.

“Ohun to n ṣẹlẹ yii ti wa lawọn ile ẹjọ.

Ṣugbọn sibẹ, eyi ko sọ pe ki ijọba ma dide lati ṣe ojuṣe rẹ lati le mu ki alaafia maa jọba.

Awọn ọrọ to wa nile ẹjọ ṣi ṣee pari nita.”

“Ijọba, ẹ da si aawọ to waye lọjọ ọdun Ileya laarin Alfa ati Pasitọ ni Iseyin lọna ati fi ọkan awọn Musulumi balẹ"

Atẹjade naa fikun pe “Bakan naa ni wahala miran to ṣẹlẹ si mọlẹbi Sheikh Sulaiman ati awọn iyawo rẹ to jẹ Ẹlẹha, pẹlu bi awọn kan ti wọn wọ aṣọ ologun, se fiya jẹ wọn.

“Ọjọ ọdun Ileya ni iṣẹlẹ ọhun waye, ati pe bi kii ba a ṣe Ọlọrun ni, ọpọ ẹmi ni ko ba sun lọjọ naa.

“A n fẹ ki iyanju wa si ohun to ṣẹlẹ lọjọ naa, ko ma si di igba ti awọn ọdọ Musulumi maa jade sita lori iṣẹlẹ naa.

“Ijọba ni lati da si, ki wọn si sọrọ sita nipa fifọkan awọn Musulumi niluu Isẹyin balẹ.

Awọn Isẹyin fẹẹ gbọ ọrọ lati ẹnu ijọba, pẹlu idaniloju pe idajọ ododo yoo waye.

“Eyi ni lati maṣe jẹ ki wahala naa tẹsiwaju, ki alaafia si wa laarin ilu.

Pasitọ naa n sọ pe ko si nnkan to le ṣẹlẹ si oun, wi pe oun mọ awọn eeyan to wa ni ipo agbara nipinlẹ Ọyọ.

“Ju gbogbo rẹ lọ, a fẹẹ gbọ ọrọ Gomina ipinlẹ Ọyọ lori iṣẹlẹ yii, gẹgẹ bi olori eleto aabo ipinlẹ yii.”

Àkọlé fídíò, UK Election: Wo ìdí tí àwọn èèyàn adúláwọ̀ ṣe mú ìdìbò ilẹ̀ UK tó ń bọ̀ ní ọ̀kúnkúndùn

Ẹgbẹ Ìmáàmù àti Alfa l'Ogbomoso sọ ìdí tí Soun kò fi jẹ́ kí Ìmáàmù Àgbà Ayilara wọ ààfin mọ́

Aworan Soun to ti waja ati Imaamu agba Ogbomosomoso

Oríṣun àwòrán, Ẹgbẹ imaamu ati alfa Ogbomoso

Awuyewuye lori ọrọ Imaamu agba ilu Ogbomoso, Sheikh Teliat Yunus Ayilara, tun ti gba ọna miran yọ lẹyin ti ẹgbẹ awọn Imaamu ati Alfa nilu Ogbomoso gbe fọto bi Soun to waja, Ọba Jimoh Oladunni Oyewumi, Ajagungbade Kẹta ṣe fi Imaamu agba Ayilara jẹ oye naa.

Ẹgbẹ Imaamu ati Alfa l’Ogbomoso fi fọto yii sita lati jẹki ọpọ eeyan to n sọ pe Soun o lagbara lori imaamu agba mọ bi ọrọ ṣe ri.

Bo tilẹ jẹ pe ọrọ naa wa nile ẹjọ, ọpọ eeyan lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu kabiyesi wi pe o doodi ki imaamu to maa gbaṣẹ lọwọ ọba alaye.

Lati oṣu Keji ọdun 2024 ni Soun o ti jẹ ki n wọ aafin mọ - Imaamu Agba Ogbomoso

Lopin ọsẹ to kọja ni iwe iroyin Daily Post sọ pe Imaamu Ayilara ni Soun, Ọba Ghandi Afolabi Olaoye ko jẹ ki oun wọ aafin lọ ṣe adura mọ lati oṣu keji ọdun 2024 yii.

Bakan ni o sọ pe Kabiyesi ko jẹ ki oun ṣe awọn nkan toun maa n ṣe tẹlẹ ninu aafin mọ.

Sheikh Ayilara fikun ọrọ rẹ pe ọjọ kẹrinla oṣu Keji ọdun 2024 ni Soun fi lẹta to fi da oun duro lati ma wọ aafin mọ ranṣẹ soun.

‘’Gbogbo akitiyan mi lati yanju ọrọ yii pẹlu Soun, pabo lo jasi.

Koda, kabiyesi ko gbe ipe mi mọ ti mo ba pe e lori foonu, ko si ọna ti mo fi le ba a sọrọ rara,’’ Ayilara lo sọ bẹẹ fun Daily Post.

Ṣaaju ni Soun ṣalaye sinu lẹta to kọ si Imaamu Ayilara pe ko gaaya fun aafin na titi ti ẹjọ to pe ọba alaye naa yoo pari.

Soun sọ ninu lẹta naa eyi ti ọpọ ileeṣẹ iroyin ni ẹda rẹ pe ai wa si aafin mọ lasiko ti igbẹjọ n lọ lọwọ yoo faye gba alaafia lori ọrọ to wa nilẹ.

Ẹgbẹ Imaamu ati Alfa l’Ogbomoso fesi sọrọ Sheikh Ayilara

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ naa fi sita eleyii ti Pakoyi Adini of Ogbomoso, Alhaji Sirajudeen Alimi buwọlu, ẹgbẹ naa ṣalaye pe Soun da Imaamu agba to gbe e lọ si ile ẹjọ duro ki alaafia le jọba ni.

Ẹgbẹ naa sọ pe ko si ẹni to le sọ ohun to le ṣẹlẹ ti Soun ko ba kọ lẹta si Sheikh Ayilara lati da a duro pẹlu ẹjọ to ti pe Kabiyesi.

‘’Lati ọjọ to ti pẹ ni Imaamu Ogbomoso ti maa n ṣe adura fun Soun ati fun alaafia ilu Ogbomoso lapapọ ni aafin.

Koda, imaamu lo maa n pin awọn nkan ti Soun ba fẹ fun awọn onimọ nipa ẹsin Islam niluu Ogbomoso fun wọn.

Diẹ lara awọn koko adura ti imaamu maa n gba ni aafin ni pe ki ọba pẹ, ki oke iṣoro ọba ti pẹtẹlẹ ati pe ki gbogbo awọn ọta ọba ni ijakulẹ.

Ṣe o ṣeeṣe ki imaamu ṣi tun maa ṣe gbogbo adura yii lẹyin to ti gbe kabiyesi lọ si ile ẹjọ?

Koko ọrọ to wa nilẹ ni pe Sheikh Ayilara ti gbe Soun lọ sile ẹjọ, amọ, ile ẹjọ ko tii dajọ lori ọrọ naa.

Niwọn igba ti ile ẹjọ ko tii gbe idajọ kalẹ, Sheikh Ayilara ko gbọdọ ṣe ohun to lodi si adehun to fọwọ si pe oun ko le rinrin ajo kuro l’Ogbomoso lai sọ fun kabiyesi, tabi ki o yan adele lati ṣoju rẹ nigba ti ko ba si nile lai sọ fun Soun.

Ni ede kukuru, lẹta ọjọ kẹrinla oṣu Keji ti Soun kọ si Imaamu agba n ṣafihan pe kabiyesi lo maa n yan imaamu agba sipo niluu Ogbomoso,’’ ẹgbẹ imaamu ati alfa ilu Ogbomoso ṣalaye.

Soun lo maa n fi imaamu agba Ogbomoso jẹ

Aworan Soun to ti waja ati Imaamu agba Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, Ẹgbẹ imaamu ati alfa Ogbomoso

Ẹgbẹ imaamu ati alfa ilu Ogbomoso ti fi oriṣiiriṣii fọto bi Soun ti fi awọn imaamu agba jẹ l’Ogbomoso sita.

Fọto akọkọ ti wọn fihan naa ni ti imaamu agba Ogbomoso, Sheikh Ayilara fun ra rẹ nibi to ti kunlẹ ṣiwaju Soun ana, Ọba Oyewumi, Ajagungbade Kẹta lọdun 2021.

Aworan Imaamu agba Ogbomoso tẹlẹ

Oríṣun àwòrán, Ẹgbẹ imaamu ati alfa Ogbomoso

Aworan Soun to waje ati imaamu agba Ogbomoso tẹlẹ

Oríṣun àwòrán, Ẹgbẹ imaamu ati alfa Ogbomoso

Lẹyin ti Imaamu Agba Ogbomoso tẹlẹ, Asheik Alamal Yekeen Ashafa, ku lọdun 2021 ni Sheikh Ayilara de ori ipo naa.

Fọto mii tawọn ẹgbẹ Imaamu ati Alfa tun gbe jade ni eyi to n ṣafihan bi Soun to ti waja ṣe fi Asheikh Ashafa jẹ Imaamu agba lọdun 2002.

Aworan mii lo tun ṣe afihan bi Ọba Oladunni Oyewumi ṣe fi Ahmad Hamzat Alawiye jẹ imaamu agba ilu Ogbomoso lọdun 1976 lẹyin iku imaamu Mahruf Alao.