Àlàyé rèé lórí bí wọ́n ṣe fi àdó olóró pa àwón àlejò níbi ayẹyẹ ìgbeyawó àti òkú ní Borno

Oríṣun àwòrán, @Harmless12345
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Borno, ni Guusu-Ila Oorun Naijiria, ti fidi ẹ mulẹ pe ikọlu ado oloro meji lo waye nijọba ibilẹ Gwoza laipẹ yii, ati pe eeyan mẹsan-an lo di oloogbe ninu awọn ikọlu ọhun.
Agbẹnusọ ọlọpaa ni Borno, ASP Nahum Daso, ṣalaye fun BBC pe awọn alejo to n bọ lati ode iyawo, pẹlu awọn to wa nibi isinku ni ado oloro naa sọ di ero ọrun.
ASP Nahum sọ pe nnkan bii aago mẹta ọsan ni ibugbamu akọkọ waye lọjọ Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹfa ọdun 2024.
'' Obinrin kan to pọn ọmọ sẹyin lo so ado oloro naa mọra, nigba to de orita Mararaba ti awọn eeyan maa n pọ si lo jẹ ki ado naa yin mọ ọn lara.
''Bo ṣe jẹ Satide jẹ kawọn eeyan maa ti ode oriṣiiriṣii bọ, ero si ti pọ lorita naa nigba ti ado oloro ọhun bu gbamu.
''O pa obinrin to so o mọra, ọmọ rẹ to pọn sẹyin ati awọn eeyan marun-un mi-in, awọn to farapa ko to mẹẹẹdogun ''
ASP Nahum lo ṣalaye bẹẹ.
Nigba to n ṣalaye nipa ikọlu keji, agbẹnusọ ọlọpaa yii sọ pe nibi ti wọn ti n ṣe adua ikẹyin fun awọn to ku ninu ikọlu akọkọ ni ibugbamu ẹlẹẹkeji tun ti ṣẹlẹ.
O ni boya lo to wakati meji lẹyin ibugbamu akọkọ ti obinrin mi-in tun fi ju ado oloro . Eyi lo ni o pa obinrin yii ati ẹnikan, awọn mi-in si farapa pẹlu.

Oríṣun àwòrán, Getty images
Ìgba kẹ́ta rèé tí ìkọlu àdó oloró yoo wáyé ní Borno láàárín oṣù mẹ́rin
Lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹrin ọdun 2024, o kere tan, eeyan mẹwaa ku ninu ikọlu ado oloro to waye nigba ti mọto kan kọja lori ado oloro ti wọn kẹ silẹ.
Awọn ẹgbẹ alakatakiti ẹsin Islam, ISWAP, ni iroyin gbe e nigba naa pe wọn ṣiṣẹ ọhun.
Ṣaaju ni ikọlu kan ti waye lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹta ọdun to kọja nitosi mọṣalaṣi kan nijọba ibilẹ Biu.
Ẹni to so ado oloro mọra lasiko ti awọn eeyan n kirun aago mẹjọ alẹ naa ku nigba ti ado naa bu gbamu.
Bẹẹ ni awọn eeyan meji mi-in farapa gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Borno ṣe ṣalaye.
Eyi to ṣẹlẹ lọjọ Satide yii lo ṣikẹta.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ologun ilẹ Naijiria n gbiyanju lati kapa awọn ti wọn n gbe ado oloro sara kiri yii pẹlu awọn mi-in ti wọn n da apa Guusu-Ila Oorun orilẹede yii laamu, sibẹ, agbegbe naa ko tura.














