Ìtàn nípa ìdí tí àwọn èèyàn ṣe n fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu

Akọ ati abo to n fi ẹnu ko ara wọn lẹnu
    • Author, William Park
    • Role, BBC FUTURE

Ariwo rẹ lo n waye nitori afihan ifẹ ninu sinima, ṣugbọn ṣe ifẹnukoni akọkọ yẹn dara to bẹẹ lati sọ pe ẹ ti fẹnu ko ara yin lẹnu? A maa n gbe gbogbo ara wa le, ṣugbọn ki lo de ti ifẹnukoni ṣe wa ṣe pataki?

Ero kan ni wi pe gẹgẹ bi ọmọde, a ni ifẹ abinibi si fifọwọ kan ẹnu ẹni: lati ori ọmu mimu, a maa n fẹ ki awọn imudara wa ni ẹnu wa.

Aba kan wa wi pe o ti mọ wa lara latilẹ lati fẹran ifẹnukoni nitori pe lati igba pipẹ, ko to di pe a gbọnju ni awọn iya wa yoo ti jẹ ounjẹ lẹnu ko to di pe wọn fi si ẹnu wa, ki a to le jẹ ẹ, eyi si ni awọn inọki to dabi eniyan maa n ṣe.

Awọn ẹiyẹ kekeeke ni wọn n gba ounjẹ lẹnu iya wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Fifi ẹnu gbe ounjẹ si ẹnu ẹlomiran maa sana ṣẹlẹ lawujọ ẹranko

"Ete wa maa n tete ni imọlara si ohun gbogbo"

Ẹlẹẹkeji ẹwẹ, ete wa maa n tete ni imọlara si ohun gbogbo.

Wọn si jẹ lara awọn ẹya ara wa ti a ko le da aṣọ bo lati gbe pamọ.

"Bi aṣọ ti a ba wọ sara ba ṣe pọ to ni yoo sọ bi iye ifẹnukoni ti a maa ni ṣe maa pọ to," eyi ni ohun ti onimọ kan, Ọjọgbọn William Jankowiak sọ.

"Bi iye aṣọ ti a ba wọ ba ṣe kere to, ni yoo sọ bi ifẹnukoni ti a maa ṣe maa kere to. Ohun kan tun ni pe laarin awọn ọlọdẹ ati awọn ero waa-wo, a kii ri ifẹnukoni.

"Awọn nikan ni ọlọdẹ to n pe ero jọ ti a ri, ti wọn fẹnuko ara wọn - Awọn agbami ifẹnukoni to gbajumọ ti wọn maa n fọwọ ra imu wọn. Wọn kii fẹnuko ara wọn, bi ko ṣe pe wọn kan maa fọwọ ra ara wọn lẹnu ni."

Ibeere naa ni wi pe - ki lo fa a?

"Ni awọn ibomiran awọn ọlọdẹ ati awọn ero-waa-wo wa, wọn kii wọ aṣọ. Eyi tunmọ si pe wọn le ni ifẹkufẹ si eyikeyi ẹya ara wọn," Jankowaik tẹsiwaju.

"Ṣugbọn nigba ti ẹ ba ti wọ aṣọ, ohun ti eniyan le ri ni awọn ibi ti a'só ko bo, eyi si ni oju eniyan."

Obinrin Innuit

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, One study found Inuit people were the only hunter-gatherer group that kissed

Ninu gbogbo aṣa mejidinlaadọsan to wa lagbaye, Jankowiak ṣawari ida mẹrindinlaadọta ti wọn n lo ete-si-ete lati fi ko ara wọn lẹnu nipa ififẹhan.

O ṣee ṣe ki idi pataki wa si ifẹnukoni atigbadegba to ti bẹrẹ lati igba iwaṣẹ.

Nipa didide sunmọ ara ẹni, a le ni imọlara ifẹ si ara wa. Eyi lo si le ṣalaye idi ti ifẹnukoni ififẹhan ti ete-si-ete kii fi saba ṣẹlẹ ninu iwuwasi eniyan.

Gẹgẹ bi iwadii kan ṣe sọ, ohun to kere si ida meji gbogbo aṣa ni wọn fi ete ṣe ifẹnukoni.

Ninu gbogbo aṣa mejidinlaadọsan to wa lagbaye, Jankowiak ṣawari ida mẹrindinlaadọta ti wọn n lo ete-si-ete lati fi ko ara wọn lẹnu nipa ififẹhan.

"Mo lero wi pe koko rẹ ni pe ifarakanra awọn eeyan le waye ni ọpọ ọna dipo ifẹnukoni,"

Ọjọgbọn yii ṣalaye. "Ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, apẹẹrẹ to lagbara kan wa - bi ẹ ba ṣe sunmọ ara si, bẹẹ ni ẹ ṣe maa ni ifẹnukoni si."

Iwe Hindu sanskrit

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ẹri iwa ifẹnukoni lo wa ninu iwe akọsilẹ atijọ ti Hindu sanskrit

"Ifẹnukonu lo fi ṣafihan igbagbọ ninu ara ẹni - lati le sunmọ awọn eniyan ti a ba nifẹ si."

Akọsilẹ ẹri to dagba julọ nipa irufẹ ifẹnukonu lo waye lati ohun ti wọn pe ni Hindu Vedic Sanskrit to ti lo ẹgbẹrun mẹta aabọ ọdun.

"Ọpọlọpọ aṣa ti wọn ni ifẹnukonu ete-si-ete bi eyi ti a mọ si ohun ti a n ṣe lonii," Sheril R Krishenbaum, to jẹ onkọwe The Science of Kissing lo sọ eyi.

"Ṣugbọn ifẹnukonu Malay ti [Charles] Darwin ṣapejuwe rẹ, nibi ti obinrin yoo ti sun silẹ, ti ọkunrin yoo si gun ori rẹ lati ni nnkan papọ - lẹyin ajọsọ."

Ni ti Trobriand Islands, to wa nitosi East Coast of Papua New Guinea, awọn ololufẹ maa ṣe ifẹnukonu nipa jijoko ojukoju, ti wọn yoo si fi irun oju kan ara wọn, "eyi ti mo lero wi pe pupọ ninu wa ni ko dun mọ lati gbọ seti," Kirshenbaum lo sọ eyi.

O fi kun un pe: "Eyi lo fi ṣafihan igbagbọ ninu ara ẹni - lati le sunmọ ẹnikeji daadaa - ati lati le sunmọ awọn eniyan ti a maa nifẹ si."

Awọn Ogongo to n ṣe ifẹnukonu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Idi ti a kii fi ri awọn ẹranko to n fẹnu ko ara wọn lẹnu?

Bi ifẹnukonu ba ni ohun pataki to n ṣe lati igba atijọ, ki lo de ti a ki fii ri awọn ẹranko lati maa fẹnu ko ara wọn lẹnu?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Fifi ẹnu ko ara ẹni lẹnu nipa ete jẹ eyi to ṣara-ọtọ ninu iwa ẹda.

Bi ifẹnukonu ba ni ohun pataki to n ṣe lati igba atijọ, ki lo de ti a ki fii ri awọn ẹranko lati maa fẹnu ko ara wọn lẹnu?

Melissa Hogenboom dahun ibeere yii fun BBC Earth lọdun 2015.

"Ọkan lara awọn idi pataki ti a fi n sunmọ ara ẹni ni lati gboorun didun ara wọn.

"Scent le ṣafihan awọn ohun pataki ti yoo wulo: irufẹ ounjẹ, arun, ipo ati apejuwe, lati sọ diẹ.

Ṣugbọn ọpọ awọn ẹranko ni wọn tete maa n gboorun ju ti wa lọ, fun idi eyi, wọn ko nilo lati sunmọ nnkan ki wọn to gboorun rẹ."

Fun idi eyi, a maa tẹsiwaju ninu ifẹnukonu - ati pe ki lo de ti awọn aṣa kan ko fi wo ibẹ?

"A ti ri ifẹnukonu pe bo ṣe n wa naa lo n poora lagbaye fun oriṣiriṣi idi pataki - lati ori arun; awọn alagbara wa ti wọn le fi ofin de ifẹnukonu laarin awọn eeyan wọn, nitori ti wọn ko lero wi pe ohun to yẹ ko jẹ koko fun wọn niyẹn," Krishenbaum lo sọrọ yii.

"Ṣugbọn ohun kan ti a ko le ka, eyi ti a n ri latigbadegba, ni pe pẹlu bi wọn ṣe n kede ifofinde to, pẹlu arun to n jẹyọ ṣe to, ifẹnukonu ṣi n pada wa."