Náírà mẹ́rin ni owó tí a kọ́kọ́ pa nídìí àwàdà ṣíṣẹ - Ẹ̀rẹ̀kẹ́niṣọ́ọ̀bù àti Alájẹjù
Náírà mẹ́rin ni owó tí a kọ́kọ́ pa nídìí àwàdà ṣíṣẹ - Ẹ̀rẹ̀kẹ́niṣọ́ọ̀bù àti Alájẹjù

Gbajúgbajà àwọn adẹ́rìnínpòṣónú, Adeyeye Adebanjo ati Timothy Agboola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Alájẹjù àti Ẹ̀rẹ̀kẹ́niṣọ́ọ̀bù ti ṣàlàyé bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ìrìàjò wọn nídìí àwàdà ṣíṣe.
Wọ́n ní ìlú Zaria ni àwọn ti jọ ń bá ìrìnàjò bọ̀ kí àwọn tó tún pàdé ní ìlú Ilesha nígbà tí àwọn padà sí ìlú bàbá àwọn.
Ẹ̀rẹ̀kẹ́niṣọ́ọ̀bù ní láti kékeré ni òun ti fẹ́ràn láti máa dáàpárá tí àwọn ènìyàn máa ń sọ wí pé Bàba Sàlá ló yẹ kí òun máa tẹ̀lé.
“Nítorí pé ẹnu mi dùn gan, àwọn àgbàlagbà ló máa ń bámi ṣọ̀rẹ́ ní ìluú Zaria.”
“Ìdí nìyí tí àwọn onítíátà fi fàmí mọ́ra.”
Alajeju ní nítorí àṣèjù máa ń pọ̀ nínú àwọn nǹkan tí òun bá ń ṣe ni wọ́n ṣe máa ń pe òun ní Alajeju kìí ṣe wí pé òun máa ń jẹun jù.






