Táńkà agbépo gbiná ní Kogi, ẹ̀mí èèyàn 20 ba lọ

Ọkọ̀ agbépo tó jóná

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ko din ni ogun eeyan to jona guruguru lasiko ti ọkọ agbepo kan gbina nipinlẹ Kogi.

Iroyin sọ pe ọkọ agbepo naa to gbe bẹtiro, ṣubu lulẹ lori afara odo Maboro nilu Ankpa, nijọba Ankpa, nipinlẹ Kogi, lẹyin ti awakọ naa sọ ijanu ọkọ nitori bureeki to da isẹ silẹ lojiji.

Isẹlẹ naa waye lẹyin ọsẹ diẹ ti awọn adigunjale yabo awọn banki kan nipinlẹ naa, ti wọn si pa awọn araalu.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun awọn akọroyin pe ni nkan bi aago mẹta aabọ ọsan Ọjọru ni ijamba ọkọ naa waye.

Wọn ni pupọ ninu awọn to ku, ni wọn jona kọja dida mọ.

“Bakan naa ni ọkọ tẹ awọn kan pa, ti ẹya ara wọn si fọn kaakiri oju popo.

Oludari ajọ ẹṣọ ojupopo, FRSC, nipinlẹ Kogi, Stephen Dawulung, sọ fun iwe iroyin Daily Trust pe awọn ko tii le sọ iye eeyan to ku.

Ọgbẹni Dawulung sọ pe ọkọ agbepo naa, bọọsi kan ati ọkọ ayọkẹlẹ mẹta, to fi mọ ọkada mẹta, lo kagbako ijamba naa.

Àwọn èrò tó ń wo ohun tó ṣẹlẹ̀

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Bakan naa ni agbẹnusọ gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi, Onogwu Muhammed sọ fun BBC pe nígbà tí ìjánu ọkọ naa bajẹ lo wọ aarin ero lọ to si ṣokunfa iku ọpọ eniyan.

Mohammed ni ọpọ dukia awọn eniyan lo run sinu ijamba naa.

O ni ijọba ti bẹrẹ igbesẹ lati ran awọn eniyan agbegbe Ankpa lọwọ lori adanu ti iṣẹlẹ naa da si wọn lọrun.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn tun ṣalaye pe niṣe ni ọkọ agbepo naa n gun awọn ọkọ miiran mọlẹ to si pa ọpọlọpọ eniyan.

Nnkan bi ọsẹ mẹta sẹyin ni awọn adigunjale yawọ awọn ile ifowopamọ kan àti agọ ọlọpaa ni ilu Ankpa ọhun ti wọn si ṣekupa ọpọlọpọ eniyan nibẹ.