Ọkùnrin kan fipá bá ọmọ ọdún 16 tó mu ọtí yó lòpọ̀ ni ilé ìjọsìn kan l'Ogun

Oríṣun àwòrán, Ogun Police
Ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan ti wọn ti fipa balopọ lẹyin to mu ọti yo lasiko ajọdun ile ijọsin kan nipinlẹ Ogun.
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti fidi isẹlẹ naa mulẹ lọjọ Ẹti.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Omolola Odutola ṣe sọ, Iya ọmọdebinrin naa lo gbe ẹjọ naa wa si ileeṣẹ ọlọpaa pe ọmọ oun, ọmọ ọdun mẹrindinlogun, ẹni to mu ọti yo lasiko ajọdun ni ile ijọsin lọjo kẹfa, oṣu kọkanla, ọdun 2023 ni Adubi nipinlẹ Ogun, ni wọn fipa ba lopọ.
Oguntola ni iya ọmọ ọhun ni oun ti lọ ti ọmọ naa mọ sọọbu kan.
O salaye pe ọmọdebinrin ni Gbenga Kolawole, ẹni ọdun mejilelọgbọn fipa ba ọmọ lopọ nitori pe o ri i pe o ti mu ọti yo.
Kolawole ni ọwọ tẹ gẹgẹ bi Oguntola ṣe sọ lasiko to n fipa ba ọmọ naa lopọ, ti ọkunrin kan ti wọn n pe ni Sunday Ibrahim si foju gan ni rẹ.
“A ti gbe ọmọdebinrin naa lọ si ile iwosan Ore Ọfe fun ayẹwo ati itọju, ti afurasi naa si ti wa ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa, nibi to ti n wi tẹnu rẹ.











