Búrẹ́dì nìkan ni oúnjẹ tí à ń rí jẹ báyìí - Àwọn ènìyàn Gaza ṣàlàyé
Búrẹ́dì nìkan ni oúnjẹ tí à ń rí jẹ báyìí - Àwọn ènìyàn Gaza ṣàlàyé

Bí ogun tó ń wáyé láàárín Israel àti Gaza ṣe ń tẹ̀síwájú, ìnìra tó ń kóbá àwọn ará ìlú ní Gaza ń kojú ń peléke si.
Ọ̀pọ̀ àwọn ará ìlú ló ń ké ìrora pé àwọn kò rí oúnjẹ jẹ àti pé búrẹ́dì ni oúnjẹ kan ṣoṣo tí àwọn ń rí jẹ báyìí.
Fún wákàtí tó pọ̀ ni àwọn ènìyàn fi ń tò lórí ìlà láti gba búrẹ́dì tí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ń pèsè fúláwà fún.
Àwọn mìíran kò tilẹ̀ ní rí búrẹ́dì gbà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti tò fún ọ̀pọ̀ wàkátì tán nítorí búrẹ́dì náà kìí tó pín fún àwọn ènìyàn tó wà lórí ìlà.
Àwọn ènìyàn ní búrẹ́dì nìkan ni oúnjẹ tí àwọn ní tí àwọn ń jẹ ní àsìkò yìí.
Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN ní kò sí bí àwọn ènìyàn ṣe lè dáná tí wọ́n bá ti ẹ̀ fẹ́ se oúnjẹ mìíràn kò sí ohun èlò tí wọ́n fi máa sè é nítorí gbogbo ilé wọn ni àdó olóró ti bàjẹ́.






