Kí ló ṣẹlẹ̀ láàárín Gani Adams àti Sunday Igboho tí Ilé ejọ́ fi ń wọ́gilé ẹjọ̀ wọn?

Aworan Sunday Igboho ati Iba Gani Adams

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo to n jokoo niluu Ibadan ti wọgile ẹsun ibanilorukọjẹ ti Iba Gani Adams pe tako ọkan lara awọn to n lewaju ipe fun idaduro ẹya Yoruba gẹgẹ bi orilẹede labẹ aṣia Yoruba Nations, Sunday Igboho.

Ile ẹjọ tun ni ki Iba Gani Adams tun san owo to to N500,000 fun Sunday Igboho.

Iwe ẹjọ ti Adams pe pẹlu nọmba idanimọ M/1006/2004, ti agbẹjọro rẹ, Sikiru Akinrele si n soju rẹ.

Ki lo sẹlẹ laarin awọn mejeeji?

Iba Gani Adams ti pe ẹjọ tako ajafẹtọọ, to n pe fun idasilẹ Yoruba Nation, Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.

Ẹsun tí Iba Gani Adams fi kan Sunday Igboho ni pe o ko ohun oun silẹ lasìko ti oun n ba eeyan kan sọrọ lorí foonu lai gba aṣẹ lọwọ oun to si fi fọnran naa sori ayelujara.

O ni iwa naa ba oun lorukọ jẹ, to si tabuku orukọ oun.

Aarẹ Ọna Kakanfo naa ni oun n beere fun ẹtọ oun labẹ ofin Naijria.

Gani Adams beere pe ki ile ẹjọ kede iwa ti Sunday Igboho hu ninu oṣu Kẹrin ọdun 2024 nípa gbigbe ohun oun sori ayelujara lai gba aṣẹ lọwọ oun bi eyi ti ko ba ofin mu rara.

Atẹjade kan ti Gani Adams fi sita ni lati igba tí Sunday Igboho ti fi fọnran naa lede lo ti n tabuku oun lorí ayelujara.

Ṣaaju ni Sunday Igboho ti kọkọ wọ Gani Adams lọ síle ẹjọ fẹsùn wi pe o pe oun ní agbanipa ati pe oun lọwọ ninu iku Bola Ige ati Fryo.

'Didakẹ mi ko ṣe bii ti ojo- Iba Gani Adams

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bẹẹ ba gbagbe, Sunday Igboho ati Tayo Ayinde ti kọwe ẹjọ ransẹ si Iba Gani Adams lati wa wi tẹnu rẹ lori ohun kan to jade nibi to ti n fẹsun kan awọn mejeeji pe wọn ti gba owo lati ṣeku oun.

Bakan naa ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun Gani Adam, Kehinde Aderemi fi lede, o sapejuwe fọnran ohun gẹgẹ bii adọgbọn si

Bakan naa lo ni ẹjọ ti Igboho ati Ayinde pe lo jẹ eyi ti wọn lẹdi apo pọ lati fi ja irawọ Adams ni igboro aye.

"O ti han gbangba pe Igboho ati Ayinde ko fẹ ki alaafia jọba lẹyin ti Ooni, Ọba Adeyeye Ogunwusi ti ba wa sọrọ."

"Idi ti mo fi dakẹ ninu gbogbo rogbodiyan yii ti Igboho ati Ayinde gbe kalẹ kii ṣe nitori mo jẹ ojo sugbọn nitori ọwọ ti mo ni fun Ooni ti ile-ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi ati awọn oriade mii ni ilẹ Yoruba ti wọn dasi ọrọ yii.

"Sugbọn pẹlu bi irọ ṣe n jade lori ọrọ mi, mo ro pe asiko ti to lati jade sita sọ bii nnkan ṣe jẹ.

"Botilẹ jẹ pe awọn agbẹjọro mi ti ṣe ohun to tọ, mo tun ni lati tan imọlẹ si ohun ti wọn ka silẹ nitori irọ lasan ni, to si jẹ ọrọ kan to waye laarin emi ati aburo ọrẹ mi kan to wa ni America, lọ̀dún 2021..

"Ọmọkunrin ọhun lo da ọrọ naa silẹ pe oun fẹ ki alaafia jọba laarin emi, Igboho ati awọn eeyan kan.

Lasiko ti ijiroro ipẹtu sija ọhun si n lọ lọwọ, ni darukọ awọn eeyan meji naa ninu alaye rẹ."

Aarẹ Gani Adams fikun pe gbogbo ọrọ nipa Tayo Ayinde to wa ninu ohun naa lo jẹ irọ.

Ki ni ile ẹjọ sọ?

Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Adajọ Ademola -Salami ni lẹyin atotonu awọn agbẹjọro mejeeji, ọpọ nkan lo fara han sita.

Salami ni igun Iba Gani Adams kọ lati fi ẹri le lẹ pe lootọ ni Sunday Igboho ka ohun silẹ lasiko to n sọrọ lori foonu.

Pẹlu bi ko ṣe si agbẹjọro kankan to wa soju Iba Gani Adams ni ile ẹjọ, adajọ wọgile ẹjọ naa, to si ni ki Iba Gani Adams san owo toto N500,000 fun Sunday Igboho.