Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dóòlà ọmọ Yorùbá kan àti India mẹ́ta l‘Ògùn

Abiọdun Alamutu lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ

Oríṣun àwòrán, Bankole Taiwo/Whatsapp

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ṣalaye lẹkunrẹrẹ bi wọn ṣe doola ẹmi awọn mẹta kan ti awọn ajinigbe jigbe wọnu igbo lọ lọjọ Aiku to kọja yii lopopona Sagamu si Ijẹbu-Ode.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abiọdun Alamutu sọ pe ọmọ Yoruba kan ati ọmọ orileede India mẹta ọtọọtọ ni wọn jigbe lasiko ikọlu naa to waye ni nnkan bi agogo meje kọja iṣẹju mẹwaa alẹ.

Alamutu lo sọ eyi di mimọ lasiko to n ṣalaye lẹkunrẹrẹ bi ikọ ọlọpaa to n gbogun ti iwa ijinigbe ṣe koju awọn ajinigbe ọhun, ti meji ti dero ọrun fun awọn akọroyin ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Eleweran niluu Abẹokuta l’Ọjọru, ọsẹ yii.

Ninu ọrọ rẹ, Alamutu ṣalaye pe “Lọgbọn ọjọ, oṣu kẹfa, ọdun 2024, awọn ọlọpaa ẹkun Ikẹnnẹ gba ipe pajawiri nipa iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni nnkan bi agogo meje kọja iṣẹju mẹwaa ni itosi ikorita Delabo to wa lopopona marosẹ Ṣagamu si Ijẹbu-Ode.

“A gbọ pe awọn agbebọn ti igbagbọ wa pe ajinigbe ni wọn, ni wọn tẹle mọto jiipu Toyota RAV4 alawọ eeru to ni nọmba idanimọ AGL 16 JE.

“Awọn agbebọn ọhun ni wọn yọ lojiji ninu ọkọ ayọkẹlẹ Venza ti ko ni nọmba idanimọ, ti wọn si yinbọn mẹrin si taya apa ibi ti awakọ wa niwaju ati ẹyin, eyi to mu ki mọto ọhun duro ni tipatipa.

“Loju ẹsẹ ni wọn ti wọ awọn to wa ninu mọto ọhun bọ silẹ, ti wọn si ko wọn wọnu mọto wọn, ko to di pe mori le ọna Ijẹbu-Ode.

“Bi a ṣe gbọ ipe pajawiri yii ni ikọ ọlọpaa to n gbogun iwa ijinigbe ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ti dide lati le awọn afurasi naa lọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“Nipa iṣẹ iwadii, wọn kofiri awọn afurasi ọhun ninu igbo ti wọn sapamọ si. Bi awọn naa ṣe ri ina mọto ọlọpaa ni wọn ti koju ibọn si wọn, ti ọrọ si di bi o ko le lọ, ki o yago lọna.

“Ibọn awọn ọlọpaa kogberegbe yii pada bori ti awọn ajinigbe yii, ti afurasi meji ti dero ọrun lasiko ija ajaku akata naa, ati pe awọn yooku to fara gbọta ri aaye lati na papa bora pẹlu ọgbẹ ọta ibọn.”

Alamutu wa fi kun ọrọ rẹ pe awọn ni anfaani lati gba awọn ti wọn jigbe naa kuro ni ahamọ wọn, ati pe ọmọ Yoruba kan, ọmọ ilẹ India mẹta ni awọn eeyan naa, ti wọn si ti wa lọdọ awọn mọlẹbi wọn pada.

Ibọn to gba ọta ibọn mọkandinlaadọfa, ibọn AK 47K marun-un ati ibọn AK 47K magazines, to fi mọ foonu meji ni wọn ri ko kuro nibi ikọlu ọhun.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe ẹmi ati dukia araalu jẹ ileeṣẹ ọlọpaa logun pupọ, idi ree to fi ni awọn ti dari ikọ ọlọpaa si opopona ọhun lati maa bojuto ọrọ eto aabo nibẹ.

Bẹẹ lo rọ araalu lati tete fi to awọn leti bi wọn ba kofiri ẹnikẹni to n gbe ọgbẹ ọta ibọn kaakiri.

Oga olopaa lasiko to n fi awon ohun ija oloro ti won ri gba han awon akoroyin

Oríṣun àwòrán, Bankole Taiwo/Whatsapp

Awon ohun ija oloro

Oríṣun àwòrán, Bankole Taiwo/Whatsapp

Alamutu ati awon olopaa re

Oríṣun àwòrán, Bankole Taiwo/Whatsapp