Ọkùnrin tó lo ọdún 28 lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn tí kò ṣẹ̀ gba ìtúsílẹ̀

Ọkunrin ọmọ ilẹ Amẹrika kan, ti gba itusilẹ lọgba ẹwọn lẹyin to ti lo nnkan bii ọdun mejidinlọgbọn lọgba ẹwọn lori ẹsun ipaniyan ti ko ṣẹ.
Lamar Johnson, to jẹ ẹni aadọta ọdun gba itusilẹ nile ẹjọ kan ni St Louis leyin ti adajọ David Mason sọ pe ko jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an ṣaaju.
Ọdun 1994 ni wọn ṣedajọ naa fun lori iku oloogbe kan ti orukọ rẹ n jẹ Marcus Boyd.
Inu Johnson dun gidi nigba ti adajọ sọ pe ko maa lọ ile rẹ layọ ati alaafia.
Nigba to n kuro ninu ile ẹjọ ọhun, o ni “Idajọ yii lagbara, mi o si le ṣalaye bi inu mi ṣe dun to.”
Ọdun to kọja ni agbẹjọro kan, Kim Gardner pe ẹjọ pe ki wọn tu silẹ lọgba ẹwọn lẹyin iwadii kan pẹlu ajọ “Innocence Project” to fidi rẹ mulẹ pe ko mọ nnkankan nipa ẹsun ipaniyan naa.
Bi Lamar Johnson ṣe dero ile ẹjọ
Ọdun 1994 ni awọn eeyan meji kan to lo iboju yinbọn pa Marcus Boyd niwaju ile Jonhson.
Johnson sọ fun ile ẹjọ lọdun naa lọhun pe oun ko si nile lasiko ti iṣẹlẹ naa waye, nitori naa oun ko mọ nnkankan nipa rẹ.
Lẹyinorẹyin, wọn ṣedajọ ẹwọn fun lẹyin ti oṣoju mi koro kan sọrọ tako nile ẹjọ.
Eyii waye ni bi ẹlẹwọn kan ṣe sọ pe oun loun yinbọn pa oloogbe naa pẹlu afurasi mii, Phil Campbell.
Amọ ṣa, Campbell gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an lọna ati din iye ọdun ti yoo lo lọgba ẹwọn ku, wọn si ṣedajọ ẹwọn ọdun meje fun.












