Ilé ẹjọ́ wọ́gilé ìbéèrè Nnamdi Kanu láti lọ gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn, ó ní olórí IPOB náà lẹ́jọ́ láti jẹ́

Ile ẹjọ giga niluu Abuja ti palaṣẹ fun ajọ Nigeria Medical Association lati ṣe iwadii eto ilera fun olori ẹgbẹ adijagbara IPOB, Nnamdi Kanu.
Kanu, to n jẹjọ bayii ni ile ẹjọ ni o si ni anfani lati wa laye lati koju awọn ẹsun ti wọn ka si lẹsẹ.
Gẹgẹ bii ileẹjọ ṣe sọ, ajọ NMA yoo gbe igbimọ ẹlẹni mẹjọ si mẹwaa kalẹ lati ṣe ayẹwo boya lootọ ni Kanu nilo itọju tabi o ni ipenija ara.
Bakan naa ni wọn yoo ṣe ayẹwo ile iwosan ajọ DSS lati mọ boya wọn ni irinsẹ to kojuoṣuwọn lati koju iru iṣoro ilera ti Kanu ni
Ki lo ṣẹlẹ ni ile ẹjọ?
Bi igbẹjọ ṣe bẹrẹ lọjọ Ẹti, agbẹjọro Nnamdi Kanu, Onyechi Ikpeazu sọ fun ile ẹjọ pe ọjọgbọn nipa ilera, Martin Aghaji, ṣe ayẹwo nla lori ilera Kan, to si gba ni imọran pè ko w ani itọsi imojuto ati itọju.
Ikpeazu sọ eyi tako ohun DSS fi tako ibeere Kanu lati lọ gba itọju ile iwosan, ti wọn si ni wọn ko ni mu awọn dokita DSS dani fun awọn ayẹwo ti wọn fẹ ṣe fun un Kanu.
Agbẹjọro olujẹjọ ni botilẹjẹpe DSS le maa bẹru pe oṣeeṣe ikọlu waye lasiko ti wọn ba n gbe Kanu lọ si ile iwosan, ki wọn ranti pe lati igba ti wọn afurasi naa ti n wa si ile ẹjọ, kosi nnkan to jẹ pe ikọlu waye.
Nigba to n fesi, agbẹjọro ijọba, Adegboyega Awomolo, ni lotitọ ni ijọba karamọsi ilera afurasi, ti wọn si n ri daju pe o gba itọju lati igba to ti w ani ahamọ.
Awomolo ni onimọ ti Kanu nawọ mu lo parọ oogun lai fi to awọn dokita DSS ti wọn ti n tọju rẹ fun ọpọ ọdun leti.
Bakan naa, Awomolo tun bu ẹnu atẹlu bii Nnamdi Kanu ṣe pinnu lati lọ si ile iwosan Amẹrika lati lọ gba itọju.
"Ki lo de to fi jẹ pe ilu Amẹrika ni wọn mu, nigba ti wọn mọ pe ofin de afurasi lati rin irinajo bayẹn. Ki wọn fẹ fi dawa loju pe nnkan to waye tẹlẹ ko tun ni waye lẹẹkansi?" Awomolo.
O tẹsiwaju pe afurasi naa ni ọpọ awọn alatilẹyin to si ṣeeṣe ki wọn gbiyanju lati gba si lẹ.
Awomolo wa bẹ ile ẹjọ pe ki fun ijọba ni ọsẹ kan lati fun ajọ NMA ni anfani lati ṣe ayẹwo wọn.
Adajọ beere lọwọ agbẹjọro afurasi pe ṣe o tako ipe agbẹjọro ijọba, Ikpeazu ni to ba ti jẹ aṣẹ ile ẹjọ, oun ṣetan lati tẹle.
Idajọ Ile ẹjọ

Lẹyin to gbọ atotonu awọn agbẹjọro mejeeji, Adajọ Ọmọtosho sun igbẹjọ naa siwaju fun wakati meji, to si pada wa lati wa gbe idajọ kalẹ.
Adajọ ni ko si arinjiyan lori pe afurasi ni anfani lati waye pẹlu ilera lati fi jẹjọ.
O ni ṣugbọn bi afurasi ṣe faye silẹ fun ara ita lati ni anfani si ilera mu ifura dani.
Adajọ Omotosho wa palaṣẹ pe ki igbimọ ẹlẹni mẹjọ si mẹwaa dide lati ṣe ayẹwo lori Kanu ati lori pe ṣe lootọ ni pe lle iwosan DSS ko ni eronja to peye lati se itọju rẹ.
Ẹsun wo ni Kanu n jẹjọ rẹ?
Ẹsun meje ọtọọtọ ni Kanu n kawọ pọnyin rojọ rẹ niwaju ile ẹjọ giga ilu Abuja bayii.
Awọn ẹsun naa da lori igbesunmọmi ati wiwa ninu ẹgbẹ agbesunmọmi.
Ọdun 2015 ni awọn agbofinro Naijiria kọkọ fi ṣikun ofin mu Kanu, ọdun naa si ni igbẹjọ rẹ bẹrẹ.
Nigba ti yoo di ọdun2017, ile ẹjọ fun ni beeli nitori ilera rẹ ṣugbọn o na papa bora lẹyin ti awọn ọmọ ogun ya bo ile rẹ niluu Umuahia, ipinlẹ Abia.
Lọdun 2021, wọn tun fi ṣikun ofin mu lorilẹede Kenya ti wọn si gbe wa si Naijiria pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ lati wa tẹsiwaju igbẹjọ rẹ.
Lati ọdun naa wa ni Kanu ti wa ni ahamọ DSS to si n lọ sile ẹjọ lati jẹjọ.
Amọ ṣa, afurasi naa ti sọ pe oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti ijọba Naijiria fi kan oun















