'Ìjọba ti hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí wa' - ìdí rèé táwọn èèyàn Senegal fi ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Nicolas Négoce
- Role, BBC News, Dakar
Nnkan o fara rọ pẹlu eto oṣelu orilẹede Senegal lasiko yii.
Nnkan iwuri lo maa n jẹ fawọn ọmọbibi orilẹede naa pe Senegal jẹ ọkan awọn orilẹede Africa ti eto oṣelu ijọba awarawa ti fidi mulẹ julọ.
Amọ, ọrọ ko rii bẹ mọ lẹnu bi ọjọ mẹta yii.
''Ero wa ni pe Aarẹ Macky Sall ti da wa,'' awọn ẹgbẹ imaamu kan lo sọrọ yii ninu mọṣalaaṣi kan ni Dakar tii ṣe olu ilu Senegal nipa rogbodiyan to ṣẹlẹ lagbo oṣelu orilẹede Senegal ni bii ọsẹ kan sẹyin nigba tawọn aṣofin ṣe atilẹyin fun Aarẹ Sall lori igbesẹ rẹ lati sun eto idibo aarẹ to yẹ ki o waye loṣu yii si oṣu Kejila.
Akọwe agba awọn imaamu, Ismael Ndiaye, sọ pe ''aarẹ gbọdọ ṣe agbeyẹwo ọrọ yii.
Ko tii ṣẹlẹ ri pe ki orilẹede Senegal sun eto ibo aarẹ siwaju.
Wọn ti huwa ọdalẹ fun wa.''
Ẹsin musulumi lo jẹ ẹsin to fẹsẹ rinlẹ ju lorilẹede Senegal.
Iru ọrọ yii to n jade lẹnu awọn olori ẹsin bayii ti wọn ti pẹtu si aawọ oṣelu tẹlẹri maa n ni ipa to pọ ni Senegal.
Ọrọ wọn n ṣafihan ibinu awọn olufẹhonuhan ti n ṣe wẹ iwọde loju popo.

Oríṣun àwòrán, AFP
Aarẹ Sall ti ṣalaye idi abajọ wi pe sisun eto idibo aarẹ siwaju ṣe pataki lati yanju aawọ to wa lori awọn oludije to koju oṣunwọn lati dije ninu eto idibo naa, lẹyin ti wọn ti fofin de ọpọ oludije lati inu ẹgbẹ alatako.
Amọ, ọpọ awọn olufẹhonu lo ri igbesẹ naa gẹgẹ bi ọna fun Aarẹ Sall lati le wa ni ọfiisi aarẹ ju ọjọ keji oṣu Kẹrin to yẹ ki saa keji rẹ pari lọ.
Ninu ifọrọwerọ ti o ṣe lẹyin ti o kede pe ijọba ti sun eto idibo naa siwaju, Aarẹ Sall ṣalaye pe kii ṣe erongba oun lati wa ni ijọba ju asiko ti saa keji oun pari lọ.
''Ko si ohun miran ti mo n wa ju pe ki alaafia jọba ni orilẹede Senegal lọ.
Mi o fẹ ki rogbodiyan bẹ silẹ ni Senegal lẹyin ti mo ba kuro lori aleefa tan,'' Sall lo sọ bẹẹ.
Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako ko gba ọrọ yii gbọ papaa julọ pẹlu bi Sall funra rẹ ṣe tako erongba aarẹ Senegal tẹlẹ ri, Abdoulaye Wade, lati dije fun sa kẹta lọdun 2012.
Sall sọ nigba naa pe ''ko ṣeeṣe ki aarẹ ki aarẹ fikun asiko to yẹ ki o lo ni ọfiisi.''
Sall to jẹ olootu ijọba nigba ti Wade jẹ aarẹ sọrọ yii lasiko ipolongo ibo lọdun 2011.
Eeyan mẹta lo ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti iwọde bẹ silẹ kaakiri orilẹede Senegal ni bii ọsẹ kan sẹyin.
Akẹkọọ fasiti Gaston Berger lo kọkọ ku ninu ikọlu pẹlu awọn ọlọpaa lapa ariwa ilu Saint-Louis nigba ti wọn yinbọn pa ẹnikeji ni Dakar.
Ọjọ Abamẹta tii ṣe ọjọ keji ni ọmọ ọdun mọkandinlogun ku, gẹgẹ bi akọsilẹ nile iwosan niluu Ziguinchor, to jẹ ọdọ ẹgbẹ alatako.
Ọpọ awọn olugbe ilu Dakar ni iwọde to n lọ lọwọ ti n kọ lominu.
Fanto Diallo to ba BBC sọrọ sọ pe ''nnkan itiju nla ni eyi.
Kii ṣe ọba ni o n ṣe olori wa ni Senegal, mi o le ra nnkan ti mo fẹ ra lẹyin ti mo wa si igboro lonii.''
Adamadou Baye ati ọrẹ rẹ, Aminata Issete, ti wọn jọ jade si igboro ilu Dakar ni otitọ ni ọrọ naa.
''A gbọdọ fi ẹhonu wa han ni wọrọọwọ, a ni lati ṣe nnkan lori ọrọ yii.
Ohun to n ṣẹlẹ ni ipalara fun emi gẹgẹ bi ẹnikan,'' Baye ṣalaye.
Issete ni ''o ti su wa, kilode to bẹẹ gan an pẹlu orilẹede wa?
Ki lo n ṣe aarẹ wa yi gan an? A fẹ dibo yan aarẹ tuntun.''

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọgunlọgọ ọdọ lo wa loju popo ti wọn n ṣe iwọde ni Senegal.
Bakan naa ni wọn n pin oriṣiiriṣii fidio ati fọto lori ayelujara lati fi ẹhonu han.
Ọpọ awọn ọdọ to n ṣe ifẹhonu han yii lori airiṣẹ ṣe lo wa lara awọn to n ṣe atilẹyin fun adari ẹgbẹ alatako, Ousmane Sonko, ti wọn ti yọwọ rẹ ninu eto ati dije fun ipo aarẹ nitori idajọ to gba lori ẹsun ibanilorukọjẹ.
Sonko ti jẹjọ lori oniruuru ẹsun ti wọn fi kan an, koda, o ti lọ sẹwọn fi ẹsun igbimọ pọ pẹlu awọn agbesunmọmi lati doju ijọba bolẹ.
Amọ, Sonko ẹni ọdun mọkandinlaadọta sọ pe oṣelu lo wa nidi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun.
Erongba rẹ lori eto ọrọ-aje Senegal lo n kọ ọpọ awọn alẹnulọrọ orilẹede Senegal ninu.
Amọ, ọpọ eeyan ni Senegal ni wọn ti ṣe atilẹyin fun un.
Sonko maa n sọrọ tako ibaṣepọ Senegal pẹlu orilẹede France ko orilẹede lẹru.
Ijọba amusin tẹlẹ ri naa fẹ ki Senegal da nina owo CFA franc duro, to jẹ owo ti orilẹede mẹrinla n na nilẹ Africa.
Ọpọ eeyan lo ti sọ pe igbesẹ yoo jẹ ki eto ọrọ aje dẹnu kọlẹ.
O ṣeeṣe ki oṣu mẹsan an si eto idibo fun ijọba to wa lode lanfani lati wa ẹlomiran fi rọpo olootu ijọba, Amadou Ba ẹni ti Aarẹ Sall fẹ amọ ti ọpọ ri gẹgẹ bi ẹni ti ko yẹ fun ipo aarẹ.
Sisun eto idibo naa siwaju tun le ṣẹnu 're fun olori ẹgbẹ alatako, Karim Wade to jẹ ọmọ aarẹ tẹlẹ ti wọn ti yọ oun naa kuro ninu idije fun ipo aarẹ tori o jẹ ọmọbibi orilẹede Senegal ati France eyi ti ofin ko faye gba

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma/BBC
Agbẹnusọ ijọba, Abdou Karim Fofana, ti fidi rẹ mulẹ pe Aarẹ Sall ko ni ba orukọ ara rẹ jẹ pẹlu oṣu diẹ toku fun un lati lo gẹgẹ bi aarẹ Senegal.
Fofana ni ''ti eeyan ba jẹ olori, eeyan ni lati gbe awọn igbesẹ kan ti ko ba ọpọ eeyan lara mu.
Aarẹ Sall ṣe ohun to ṣe lati daabo bo orilẹede Senegal ni tori ẹni to mọ ohun ti o n ṣe ni o jẹ.''
Pẹlu bi wọn ti yọ Sonko ninu awọn oludije fun ipo aarẹ, ti ọpọ eeyan si gbagọ pe ijọba lo ẹka eto idajọ lati yọwọ rẹ kuro ninu idije ọhun, o ṣeeṣe rogbodiyan to n lọ lọwọ ma ni ojutu.
El-Hadji Omar Diop to jẹ onimọ nipa ofin ṣalaye pe Aarẹ Sall le fipo silẹ lọjọ keji oṣu Kẹrin gan an ti ile igbimọ aṣofin yoo si maa ṣe ijọba lọ, eto idibo si le waye laarin oṣu meji.
Mamadou Faye to ni ọmọ mẹta sọ o yẹ ki gbogbo rogbodiyan to ti waye ti jẹ ẹkọ fun onikaluku bayii tori oun ko le lọ sibi iṣẹ bayii.
Faye ni ''ko si ẹni to maa ran mi lọwọ, ọrọ naa ti su wa, ohun ti a fẹ ni lati le pese ounjẹ fun ẹbi wa.''
















