Àwọn onímọ̀ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó fa ooru àmújù ní Nàìjíríà àtàwọn ilẹ̀ Adúláwọ̀ míì

Aworan ọmọbinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Abọ iwadii awọn onimọ sayẹnsi kan ti fihan pe ayipada oju-ọjọ eyi tawọn eeyan ṣe okunfa rẹ lo fa ooru amuju to mu lẹkun iwọ-oorun ilẹ Afrika loṣu Keji to kọja ninu ọdun 2024 yii.

Awọn ẹgbẹ oluwadii sayẹnsi ti wọn jẹ ominọ nipa oju-ọjọ fidi rẹ mulẹ lẹyin iṣẹ iwadii wọn pe iru ooru to maa n mu loṣu Kẹta tabi oṣu kẹrin lo mu ninu oṣu Keji lẹkun iwọ oorun Afrika papaa julọ lorilẹede Naijiria, Ghana, Togo atawọn orilẹede mẹfa mii.

Iwadii awọn onimọ sayẹnsi ọhun fihan pe oju ọjọ gbona to iwọn 40°C laarin kan ninu oṣu Keji ọdun 2024 yii.

''Ooru amuju maa n pa eeyan diẹ diẹ ni, awọn agbalagba lo maa n ṣakoba fun julọ atawọn ti wọn ba ni aisan lara to fi mọ awọn to n ṣiṣẹ nita gbangba,'' Maja Vahlberg to jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa ewu to n ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ Red Cross lo sọ bẹẹ.

Ti ẹ o ba gbagbe, iru ooru yii lo mu lasiko idije Afcon 2023 to waye lorilẹede Ivory Coast laarin oṣu kinni si ekeji.

Ooru naa pọ debi wi pe awọn agbabọọlu ni lati maa mu omi loorekoore nigba ti ere bọọlu ṣi n lọ lọwọ lati pa ongbẹ to n gbẹ wọn.

Ajọ to n ri si ọrọ oju-ọjọ ni orilẹede Naijiria ati Ghana naa kilọ fawọn araalu lori ooru amuju to n mu.

Amọ, ko si ọkankan ninu awọn orilẹede ti ooru ti mu ju yii to ni eto kan gboogi lati wa ojutuu si iṣoro ooru to n mu.

''O ti han gbangba pe ayipada oju-ọjọ lo n ṣokunfa bi ooru ṣe n mu amuju bayii lẹkun iwọ -oorun ilẹ Africa.

Nigba kugba ti ayipada oju-ọjọ ba ti ṣẹlẹ lagbaaye ni ooru amuju maa n mu bi eyi to mu loṣu Keji,'' Wasiu Adeniyi Ibrahim to jẹ ọgagba ajọ to n wo bi oju ọjọ yoo ṣe ri lo sọ bẹẹ.

Awọn onimọ sayẹnsi ti kilọ pe bawọn eeyan ko ba dẹkun awọn ohun to n ṣokunfa ayipada oju-ọjọ bi eefin epo rọbi to n lọ soju ọrun, ooru amuju yoo maa mu lọdun meji meji ni ẹkun iwọ oorun Africa.

Oṣu Keji ọdun 2024 lo tii gbona julọ lagbaaye, ohun naa lo si jẹ oṣu Kẹsan an ti ooru yoo mu lera lera.