Namibia yan obìnrin gẹ́gẹ́ bí igbákejì Ààrẹ fún ìgbà àkọ́kọ́

Netumbo Nandi-Ndaitwah

Oríṣun àwòrán, Netumbo Nandi-Ndaitwah

Orílẹ̀ èdè Namibia ti ní Ààrẹ tuntun lẹ́yìn tí Ààrẹ Hage Geingob papòdà.

Ààrẹ tuntun náà ni Nangolo Mbumba, tó jẹ́ igbákejì Ààrẹ tó papòdà.

Ní àárọ̀ ọjọ́ Àìkú ni Hage Geingob jẹ́ Ọlọ́run nípè ní ilé ìwòsàn kan tó ti ń gba ìtọ́jú ní olú ìlú orílẹ̀ èdè náà, Windhoek.

Lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí Geingob jáde láyé ni wọ́n búra wọlé fún Ààrẹ Nangolo Mbumba?

Ààrẹ Mbumba ni yóò wà nípò títí tí wọ́n fi máa ṣètò ìdìbò lọ́dún yìí.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ lásìkò tí wọ́n ń búra fún un, ààrẹ Nangolo Mbumba ní òun kò ní díje dupò Ààrẹ.

"Mi ò ní sí nílé lásìkò ìbò, nítorí náà ẹ lọ fi ọkàn balẹ̀."

Nígbà tó ń kan sáárá sí Ààrẹ tó papòdà, ó ní ètò ìṣèjọba rẹ̀ ló jẹ́ kí orílẹ̀ èdè náà ṣì wà ní àlàáfíà di àsìkò yìí.

Ó ní òun mọ iṣẹ́ tó wà nídìí ẹrù tí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rú náà àti pé ipa Ààrẹ tó papòdà náà ni òun yóò tọ̀.

Bákan náà ló kéde ẹni tí yóò bá ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí igbákejì.

"Ẹ̀yin èèyàn Namibia, bí mo ṣe ń gba ipò Ààrẹ lónìí, inú mi dùn láti Netumbo Nandi-Ndaitwah gẹ́gẹ́ bí igbákejì Ààrẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Ta ni Netumbo Nandi-Ndaitwah, Obìnrin tó kọ́kọ́ di igbákejì Ààrẹ ní Namibia?

Netumbo Nandi-Ndaitwah ati aare Nangolo Mbumba

Oríṣun àwòrán, NAMIBIA PRESIDENCY/Netumbo Nandi-Ndaitwah

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí obìnrin yóò di igbákejì Ààrẹ ní orílẹ̀ èdè Namibia bí Ààrẹ ṣe kéde Netumbo Nandi-Ndaitwah, ẹni ọdún méjìléláàádọ́rin.

Netumbo Nandi-Ndaitwah jẹ́ obìnrin tó ti kópa ribiribi nínú òṣèlú Namibia.

Òun ni igbákejì Ààrẹ The South West Africa People's Organization tí wọ́n mọ̀ SWAPO party ní Namibia.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà lórí ayélujára Namibia Parliament, ní ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹwàá ọdún 1952 ni wọ́n bí Netumbo Nandi-Ndaitwah ní Onamutai, ẹkùn Oshana.

Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè onímọ̀ kejì (Masters of Arts degree) nínú ìmọ̀ Diplomatic Studies.

Ó jẹ́ olóṣèlú tó di ọ̀pọ̀lọpọ̀ ipò òṣèlú mú pàápàá nínú ẹgbẹ́ wọn.

Ẹ̀ẹ̀meje ló ti lọ ṣojú ẹkùn rẹ̀ ní ilé aṣòfin àpapọ̀ orílẹ̀ èdè náà láti ọdún 1995.

Ní ọdún tó ń bọ̀ ló yẹ kí sáà tó ń lò lọ́wọ́ ní ilé aṣòfin yẹ kó parí.

Ó wà lára àwọn tó ń léwájú níbi ètò ìdìbò tí yóò wáyé lórílẹ̀ èdè náà nínú oṣù Kẹsàn-án ọdún 2024.

Ó ti fìgbà kan jẹ́ igbákejì Olóòtú ìjọba Namibia àti Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè.

Bákan náà ló tún ti ṣe Mínísítà fọ́rọ̀ àwọn obìnrin, Mínísítà fétò ìròyìn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ta ni Ààrẹ Nangolo Mbumba?

Aare Namibia

Oríṣun àwòrán, NAMIBIA PRESIDENCY

Ní ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹjọ ọdún 1941 ni wọ́n bí Nangolo Mbumba gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà lórí ìtàkùn ayélujára iléeṣẹ́ ìjọba Namibia.

Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Southern Connecticut State University ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ni ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè lọ́dún 1971.

Lẹ́yìn náà ló gboyè onípò kejì ní ilé ẹ̀kọ́ University of Connecticut nínú ìmọ̀ Biology.

Ààrẹ Nangolo Mbumba ti darí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iléeṣẹ́ Namibia.

Lára àwọn iléeṣẹ́ tó ti ṣàkóso rẹ̀ ni iléeṣẹ́ ètò ọ̀gbìn, omi àti ìdàgbàsókè ẹsẹ̀ kùkú láàárín ọdún 1993 sí 1996.

Bákan náà ló darí iléeṣẹ́ ètò ìsúná láàárín ọdún 1996 sí ọdún 2003.

Bẹẹ̀ náà ló ti ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́, ìròyìn, ààbò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ní ọdún 2012 ló di akọ̀wé ẹgbẹ́ SWAPO títí di ọdún 2017.