Basorun Akinade Ayoola Yusuf: Ìsìnkú Aláàfin Oyo àti Ooni Ile Ife yàtọ̀ nílẹ̀ Oodua

Àkọlé fídíò, Basorun Akinade Ayoola Yusuf: Ìsìnkú Aláàfin Oyo àti Ooni Ile Ife yàtọ̀ nílẹ̀ Oodua

Ajiṣe bi Oyo laa ri- Basorun Yusuf Akinade Ayoola

Lati igba ti erin Iku Baba Yeye, Oba Lamidi Adeyemi keta ti wo Irú ẹ̀dá wo ni Lamidi Adeyemi? Aláàfin tó rí ìbẹ̀rẹ̀ àti opin sáà gómìnà mọ́kànlélógún l‘Oyo ni awọn eeyan ti n beere ibeere to pọ.

Eyi lo mu ki BBC Yoruba gbera lọ si Oyo lọ ṣe iwadii to yẹ nipa Abobaku, irufẹ eto isinku ti wọn n sin awon alaafin saaju asiko ayelujara ti a wa yii ati ọna ti wọn n gba fi Oba mii jẹ ni Oyo ile ati Oyo Oko pẹlu pataki awọn Oyomesi.

Kini Basorun Ayoola sọ nipa Eto Isinku Alaafin Atanda Olayiwola?

Basorun Yusuf Akinade Ayoola ṣalaye fun BBC Yoruba pe ki gbogbo araye le rii pe ara Alaafin Lamidi Adeyemi keta ni wọn fẹ lọ sin ni wọn ṣe gbe e sita.

O ni ki wọn le mọ pe o gbagbọ naa si ni Oyomesi ṣe jẹ ki awọn elesin Islam wẹ Oba Lamidi ki wọn si kirun si Iku Baba Yeye.

O ni pe ni kete ti awọn Musulumi kirun si alaafin tan naa ni awọn si ti gbe ara Alowolodu wọ aafin lọ lati fi yanju eto to ku.'Ètò ayẹ́yẹ́ ìsìnkú Oba Lamidi Adeyemi kòí tíì wáyé, àfọ̀mọ́ Aàfin ń lọ lọ́wọ́'

Eto Isinku Alaafin Adeyemi

Wo ìtàn ọmọ Olokunẹṣin tí wọ́n jẹ́ Abọ́bakú gbogbo Alaafin lati iran de iran:

Olootu Oyomesi, Basorun Yusuf Ayoola ṣalaye ni kikun lori ohun to ṣokunfa Abobaku ni aafin Oyo bẹrẹ lati ọdọ àwọn Alaafin to ti lọ darapọ mọ awọn Alaseku.

Bakan naa ni O tun sọ nipa idile Olokunẹsin to n jẹ Abobaku fun gbogbo Alaafin Oyo lati igba iwase.

O pari rẹ pe, eto Abobaku ti pari ni Oyo, ati pe, ẹni to yẹ ko ba alaafin Lamidi Adeyemi rin lasiko yii ṣi wa laaye ati ni alaafia.Ta ni Yorùbá ń pè ní Abọ́bakú?

Mọ̀ síi nípa owé: Ajiṣe bi Oyo làá rí.......

Basorun ilu Oyo sọrọ ni kikun pe gbogbo nkan nipa Oyo lo yatọ.

O ni pe ilu Oyo ile ati Oyo Oko to gbe Oyo duro lonii ni eto, aṣa, iṣeṣe a[ti igbagbọ ninu awọn Alalẹ.

O sọ idi ti wọn ko ṣe sin Oba ni oku oru rara.

Alaafin

Oríṣun àwòrán, Others

Ta ló maá dé adé Alaafin Oyo lẹ́yìn Oba Lamidi Adeyemi?

Basorun to jẹ ọlọwọ ọtun Alaafin to tun jẹ olori adari Oyo lati igba ti Oba Lamidi Adeyemi ti waja ti sọrọ lori ẹni ti ade kan lati de.

Basorun Ayoola sọ fun BBC Yoruba pe titi di ilẹ to mọ loni yii, Gbogbo Oyo nile, loko ati lẹyin odi koi tii mọ ẹni ti yoo jẹ Alaafin.

Basorun Oyo

O ni eyi ko ṣeyin pe Oyo ti mọ idile to kan nitori pe, Itọsẹ lo ni Oyo

Ati pe wọn ti mọ igbesẹ aṣa ati Ifa ati bi ọrọ ṣe maa ri ṣugbọn kosi kanjukanju ninu yiyan Alaafin tuntun.

Alaafin

Oríṣun àwòrán, Oyo Archive