Garba Shehu: Inú aráàlú kò dùn sí ìwọ́dé Yoruba Nation àti IPOB tó wáyé l‘Amẹ́ríkà

Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari feto iroyin, Garba Shehu, ti bu ẹnu atẹ lu iwọde ti awọn ọmọ Naijiria kan ṣe ni orilẹede Amẹrika.
Garba ni iwọde tí ikọ Yoruba Nation ati IPOB to n ja fun ominira ẹya Igbo ṣe lati tako Aarẹ Buhari lasiko to ba awọn adari lagbaye sọrọ ni ipade Ajọ Iṣọkan Agbaye to waye ni New York ko tọna.
Garba Shehu, ninu atẹjade to fi lede ni awọn to ṣe ifẹhọnuhan naa dunkoko mọ awọn oṣiṣẹ ijọba Naijiria lasiko ti wọn fẹ wọ gbagede ipade Iṣọkan Agbaye, UN naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Dandan kọ́ ni kí o ṣe àyẹ̀wò DNA tí kò bá sí ẹni tó n bá ọ du ọmọ rẹ - Rotimi Salami
- 'Àwa Ọlọ́pàá ò lè sọ bóyá lóòtọ́ ọmọ Yahoo ló ju òkú obìnrin s'ẹ́gbẹ̀ẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì, ẹní bá mọ̀ọ́ kó fojú hàn'
- Ọlọ́pàá, Amotekun àti figilanté kán lu igbó láti wá àwọn tó pa ọlọ́pàá méjì ní báńkì Iragbiji, Osun
- 'Àyẹ̀wò ìdákọ́ńkọ́ mi gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nípa ìhùwàsí ọmọde fihàn pé Baba Ijesha fọwọ́ kan ọmọ Princess lọ́nà tí kò tọ́'
- Ìpanu ''small chops'' ló mú kí sọ́jà da omi ìdọ̀tí lé mi lórí - Corper Fidelia
- Bí o bá ń fẹnukonu ju iye ìṣẹ́jú ààyá yìí lọ, wo adúrú kòkòrò tí wàá tí ibi ẹnu kò
- Wo ohun tí ọlọ́pàá sọ nípa 'Charlie', ajá tó gé kórópọ̀n akẹ́kọ̀ọ́ fásitì AAUA jẹ l'Ondo
O ni idunkokomọni nitori ẹya ni ikọ Yoruba Nation ati IPOB ṣe ni New York, eleyii to ni ko ba ofin mu.
Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ Buhari naa ni, bi o tilẹ jẹ pe wọn ni aṣẹ labẹ ofin lati ṣe ifẹhọnuhan, amọ kii ṣe iwa to bu iyi kun ẹnikẹni lawujọ lati ma a dẹyẹ si eniyan nitori ẹya wọn.
Shehu ni asiko ti aarẹ Buhari n sọrọ lori awọn ipọnju ti orilẹede Naijiria n la kọja, ti o si n rọ awọn adari lagbaye lati dasi iṣoro wọn, ni awọn kan n ṣe ifẹhọnuhan tako aarẹ Buhari ni iwaju Ileeṣẹ Ajọ Iṣọkan agbaye naa.
'' Awọn to ṣe ifẹhọnuhan yii ti fihan pe awọn n ṣiṣẹ lodi si orilẹede Naijiria , ti wọn si n da rudurudu silẹ laarin ilu.''
''Bakan naa ni awọn eeyan yii n pa awọn ẹṣọ alaabo, ti wọn si n di awọn araalu lọwọ lati ṣe iṣẹ oojọ wọn nitori wọn fẹ gbe ijọba ara wọn kalẹ ni ọna aitọ''
Gẹgẹbi ọrọ oṣiṣẹ ijọba Buhari naa, o ni aarẹ Buhari n ṣiṣẹ takuntakun lati ri pe ko si ẹni to tẹ ẹtọ ara ilu mọlẹ, ti o si mu ọrọ oju ọjọ to n ṣe segesege lọkunkundun lọna ati mu ki ipese ounjẹ ati idẹra de ba awọn ọmọ Naijiria.
O fikun pe aṣeyọri aarẹ Buhari ko ni abawọn kankan, to fi mọ ṣiṣe iranwọ fun awọn ọmọ Naijiria kọọkan lati di ipo agba mu ni awujọ lagbaye.
''Eleyii fihan pe alaafia ati ifimọṣọkan lawujọ jẹ aarẹ Buhari logun, nitori naa kii ni ifẹ si ohun rudurudu''
''Bakan naa ni aarẹ Buhari n gbiyanju lati ri pe laipẹ awọn eniyan to jẹ ọmọ orilẹede Naijiria to n gbe ni oke okun ni anfaani lati dibo fun ẹni ti ọkan wọn yan lasiko ti idibo ba n waye lorilẹede Naijiria.''















