Pierre Buyoya: Coronavirus ni wọn ló pa ààrẹ tẹ́lẹ̀ náà lẹ́ni ọdún 71

Pierre Buyoya, ààrẹ tẹ́lẹ̀ ní Burundi

Oríṣun àwòrán, AFP

Aarẹ tẹlẹ ni orilẹede Burundi, Pierre Buyoya ti jade laye lẹni ọdun mọkanlelaadọrin.

Mọlẹbi oloogbe naa to fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC ni Buyoya dagbere faye nilu Paris ni Ọjọbọ lati ipasẹ arun Coronavirus.

Ọgagun to ti fẹyinti naa lo lo ọdun mẹtala lori aleefa lẹyin to fi ipa gba ijọba lọwọ awọn asaaju rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni osu Kẹwa ọdun 2020 ni ile ẹjọ kan nilẹ Burundi ran lẹwọn lai si nibẹ lori ẹsun pe o gba ẹmi aarẹ akọkọ ti araalu dibo yan lorilẹede naa, Aarẹ Melchior Ndadaye lọdun 1993.

Isẹlẹ naa si ni wọn lo sokunfa rogbodiyan to ran eeyan bii ẹgbẹrun lọna ọọdunrun lọ sọrun.

Pierre Buyoya

Oríṣun àwòrán, Twitter@Pierre Buyoya

Amọ Buyoya ni oun ko jẹbi ẹsun asemase kankan rara.

Ni osu to kọja ni Buyoya kọwe fipo silẹ gẹgẹ bi asoju ajọ isọkan orilẹede Afirika si ilẹ Sahel pẹlu awijare pe oun fẹ gbajumọ ọna lati wẹ orukọ oun mọ.