Kí ló mú kí àwọn ọ̀yìnbó aláwọ̀ funfun gé'run Dàda ọmọ aláwọ̀dúdú?

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọmọdebinrin alawọ dudu ilẹ Amẹrika kan ti farada ohun ti ko yẹ ki ọmọde kankan fara da pẹlu bi awọn ojugba rẹ alawọ funfunfun mẹta ṣe da dubulẹ ti wọn si ge irun ori rẹ.
Omọ ọdun mejila naa to ni irun dada lori ti orukọ rẹ n jẹ Amari Allensi ni wọn ge irun ori rẹ pelu abẹ.
Iṣẹlẹ naa waye ni akoko isinmi ni ile iwe rẹ to wa ni Springfield Virginia ni ọjọ Aje ọsẹ yii.
Amari ni awọn ọmọkunrin ojugba ohun naa ni wọn pe oun si ibi iṣere ti wọn si bẹnu abuku lu irun ori oun ki wọn to bẹrẹ si ni ge.
O ni iṣẹlẹ naa waye ni ile iwe Immanuel Christian ,ti aya Aare orilẹ ede Amẹrika ti n ṣiṣẹ olukọ.
Awọn Ọlọpaa ile iwe naa ati Agbofinro ilu ti n ṣe iwadii ọrọ naa.

Allen ṣalaye pe awọn ọdọkunrin naa ni wọn wa ba oun ti wọn si mu oun ni panpa mọra.
O tesiwaju pe n ṣe ni wọn fi ọwọ bo oun lẹnu ti wọn si n sọ oriṣiriṣi ọrọ ti wọn si bẹrẹ sini ge irun ori oun.
Ninu alaye naa lo ti sọ pe, gbogbo ounjẹ oun ni wọn jẹ ti wọn si fi oun ṣe ọpọlọpọ yẹyẹ.
Ni ọjọru ọsẹ yii ni awọn ẹbi rẹ ṣakiyesi pe irun rẹ ko gun mọ bi ti tẹlẹ ti iyatọ si wa ninu irun naa.
O ni, ki ile iwe le awọn ọmọ yii kuro ni ile iwe nitori irun naa n dun oun gidi.
Kini ile iwe rẹ sọ
Ile iwe naa ṣalaye pe, awọn ko fi ọrọ ọmọ naa ṣere rara to fi mọ eto ilera wọn ti ko si faye gba idunkoko mọra ẹni
Bakan naa ni ile iwe naa ni ọrọ naa mu wọn lomi pupọ ti wọn si n ran ẹbi naa lọwọ lati ri aridaju ẹri ọrọ naa.
Ile iwe yii n san ọpọlọpọ owo dọla lọdọọdun ni bi ti Karen Pence, ti o jẹ iyawo Igbakeji Are orilẹ ede naa ti n ṣiṣẹ.
Di school, wey di Allen family dey spend $12,000 evri year, na wia Karen Pence - di wife of di Vice-President Mike Pence dey teach art part-time.












