Kaduna Children-Méje ni ọwọ ti tẹ nínú àwọn Afunrasí ìka Olùkọ Kaduna - Ọlọpàá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kaduna ni awọn afunrasi to de fi ipa de awọn akẹkọ mọlẹ nile kan ti jẹwọ ohun to mu wọn ṣe bẹ.
Awọn ika olukọ naa ni pe ọmọ ti kii gbọrọ lawọn n de mọlẹ,koda eyi to ba kọ eti kun a ma fi iku ṣefajẹ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ile isẹ BBC ni ọrọ yi ti jẹyọ lati ẹnu alukoro ọlọpaa Kaduna,ọgbẹni Yakubu Sabo.
Sabo ṣalaye pe, lara awọn ọmọ naa ni ko ni imi ati okun ninu mọ latari airi ounjẹ jẹ daada da.
O ni ọpọlọpọ wọn ni wọn ti gbẹmi mi nitori pe wọn ko ni anfaani lati jade sita ninu ahamọ ti wọn bara wọn.
Ọga ọlọpaa naa tẹsiwaju pe lara awọn ijẹwọ ọkan lara wọn ni pe, iku ni ọmọ ti ko ba gbọnran maa n ri.

Oríṣun àwòrán, BBC Africa
Nigba ti ile Iṣẹ BBC Yoruba n ba kọmiṣọnna fun eto idagbasoke awujọ ni ipinlẹ naa, Hasfat Baba,sọrọ,o ni iwa naa ko boju mu.
O ni iwa ika gidi ni ẹni ti o pe ara rẹ ni Olukọ naa hu nitori pe,ọpọ awọn ọmọ wọnyii ni aisan ti n baja ti ọpọ wọn si ti gbẹmi mi.
Gẹgẹ bi o ti wi, o ni awọn obi gan ni o yẹ ki a da lẹbi ọrọ naa nitori pe ko yẹ ki wọn fi ọmọ si iru ile iwe bẹẹ.
O tun tẹsiwaju pe awọn ọmọ wonyii ni wọn maa n fi iya jẹ lainidi ti wọn si maa n pa wọn .

Oríṣun àwòrán, Police facebook
Ikọ awọn Ọlọpaa ni kaduna naa ṣalaye pe, ọpọ ninu awọn ọmọ wọnyii ni ko mọ ọna pade sile mọ ti awọn obi wọn ko si ni anfaani lati mu wọn.












