Gift Sotonye-Frank: Bó ṣe gba oyè ọ̀mọ̀wé nípa òfin, náà ló gba àmì ẹ̀yẹ

Gift Sotonye-Frank

Oríṣun àwòrán, @QUBelfast

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ọmọ Naijiria kan, arabinrin Gift Sotonye-Frank, to n kẹkọ gboye ọmọwe lẹka imọ ofin ni Queen's University to wa nilu Belfast ti gba ami ẹyẹ akẹkọ to dantọ julọ nileẹkọ naa.

Ileeẹkọ fasiti Queen's lo kede ohun iwuri yii loju opo ikansira ẹni Twitter rẹ, ti Gift funra rẹ naa si ki ara rẹ ku oriire ami ẹyẹ naa loju opo Twitter tiẹ naa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ileẹkọ fasiti yii lo mọ iriri ẹmi ifaraẹnijin, ipamọra ati ipa ribiribi ti Sotonye n ko si iwadi lori isẹda, ibalopọ ati ẹtọ ọmọniyan, paapa bo se foju sun ẹtọ awọn obinrin ati ẹtọ si eto ẹkọ fawọn ọdọbinrin ọmọ Naijiria.

Gift Sotonye-Frank, ọkọ ati awọn ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, @gift_sotonye

Lasiko ayẹyẹ ikẹkọjade lawọn ẹgbẹ akẹkọjade ileewe naa gbe ami ẹyẹ ọhun fun Sotonye, to sẹsẹ gba oye ọmọwe, PHD nile ẹkọ ọhun, ami ẹyẹ naa si ni ikọkanlelogun iru rẹ, pẹlu atilẹyin ile ifowopamọ kan.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Àkọlé fídíò, 'Àjẹ́, eégún, kí ni wọn ò pè mí tán tórí Vitiligo lára mi'

Ami ẹyẹ si lo n mọriri ẹnikẹni to pegede, se aseyọri tabi sisẹ sin fun ileẹkọ naa tabi fun awujọ lapapọ.