RUGA: Afenifere, Kunle Akinjide sọ̀rọ̀ lórí ìkéde ìjọba àpapọ̀ láti dáwọ́ dúró lórí RUGA

Aworan maluu ati darandaran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ijọba apapọ kede lalẹ Ọjọru pe awọ̀n n dawọ duro lori idasilẹ awọn gaa darandaran RUGA to ti n fa awuyewuye fun ọjọ diẹ sẹyin bayii

Lẹyin ti aarẹ Buhari ti kede pe ijọba apapọ yoo jami lori igbesẹ ati da awọn Gaa darandaran RUGA silẹ bayii, ẹgbẹ Afẹnifẹre ti pariwo sita pe ete lasan ni ọrọ naa nitori kii ṣe pe aarẹ ni awọn wọgile e patapata.

Ẹgbẹ Afẹnifẹre ṣalaye pe niwọn igba ti ijọba apapọ ba ṣi ni i lero ati gbe igbesẹ naa dide lọjọ iwaju, awọn ko lee fi gbogbo ara dunnu si ikede naa.

Àkọlé fídíò, Kunle Afolayan: èmi kò fẹ́ fi ogún sílẹ̀ fún ọmọ mi

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ lọjọbọ, agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, Yinka Odumakin wi pe ẹtan ni ikede ijọba apapọ naa nitori kii ṣe ijọba apapọ wọgile igbesẹ naa patapata, wọn kan n jawọ lori rẹ fun igba diẹ lasan ni.

Bakan naa ni ẹgbẹ naa tun kọminu lori ẹgbẹ kan ti wọn ni o dide lapa oke Ọya to n fun ijọba apapọ ni gbedeke ọgbọn ọjọ lati bẹrẹ eto RUGA ni gbogbo ipinlẹ Naijiria bi wọn ko ba fẹ ki awọn dana wahala silẹ.

O ni ohun ti o lee dun mọ ilẹ Yoruba ninu ni ki wọn wọgile eto naa patapata.

Àkọlé fídíò, Wòlíì Kasali sọrọ nípa awuyewuye pé o lè ìyàwó rẹ̀ jáde nílé

Ninu ọrọ tirẹ, akọwe agba ẹgbẹ awọn agba ilẹ Yoruba, YCE, Dokita Kunle Ọlajide ni igbesẹ to dara ni aarẹ gbe ṣugbọn o tun ku ni ibọn n ro.

Gẹgẹ bii ifọrọwerọ Dokita Akinjide pẹlu BBC News Yoruba, o ni o yẹ ki ijọba mọ pe ọrọ orilẹede yii ti di ti 'eyi wumi ko wu ọ'

O fi kun un pe atunto orilẹede Naijiria nikan ni ọna abays fun irufẹ edeaiyede ati awuyewuye bayii.