Chelsea kéde Frank Lampard gẹ́gẹ́ bíi olùkọ́ni tuntun

Oríṣun àwòrán, chelseafc.com
Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ti kede Frank Lampard gẹgẹ bii olukọni tuntun fun ikọ naa.
Adehun ọdun mẹta ni Chelsea ati Lampard tọwọ bọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Frank Lampard fi igba kan ri jẹ agbabọọlu ikọ naa ti orukọ rẹ ko lee parẹ laelae, oun si ni agbabọọlu to gba goolu wọle julọ fun ikọ ọhun ki o to fi ibẹ silẹ.
Ninu atẹjade kan ti ikọ Chelsea fi sita ni owurọ Ọjọbọ, oludari ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea Marina Granovskaia ni: 'Inu wa dun lati ki Frank Lampard pada si Chelsea gẹgẹ bii olukọni agba. Frank ni oye to jinlẹ gidigidi nipa ẹgbẹ agbabọọlu yii ati bi nnkan ṣe lọ si ni saa bọọlu to kọja, si ti fihan pe oun wa lara awọn ojẹwẹwẹ olukọni ti ọpọlọ wọn pe ninu ere bọọẹu afẹsẹgba.
Ọdun mẹta ni Frank Lampard lo ni Stamford Bridge, awọn alaṣẹ Chelsea si ti fi igbẹkẹle wọn han pe asiko to yẹ ẹ gan lo pada wa yii gẹgẹ bii oluksni wọn.
Nigba ti oun pẹlu n sọrọ lẹyin ti o tọwọ bọwe adehun rẹ tan, Frank Lampard ni iyi nla lo jẹ fun oun lati di olukọni agba fun ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ati pe afojusun oun bayii ni 'lati mura giri fun iṣẹ naa ati lati pese ikọ naa silẹ gidigidi fun saa ere bọọlu to n bọ lọna'
Frank Lampard n bọ si ipo naa lẹyin ti Mario Sarri to wa nibẹ tẹlẹ ti lọ darapọ mọ Juventus lorilẹede Italy.










