DSS on IPOB Akunyili killing: Ikú Dókítà Chike ṣòkùnkùn sí wá ṣùgbọ́n a o ṣé ìwádìí àwọn tó pa

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ni Naijiria ti sọ pe awọn ko mọ nkankan nipa ahesọ ọrọ to n lọ nita pe awọn lo pa Dr Chike Akunyili.
Ninu atẹjade kan ti alukoro wọn Peter Afunaya fi sita o ni awọn yoo tọ pinpin awọn to ṣeku pa ọkọ minisitali tẹlẹ naa.
''A ti gburo ẹsun kan tawọn kan fi kan wa pe awọn oṣiṣẹ wa lo pa Dr Chike Akunyili''.
''Bẹẹ na la tun ri fọnran fidio kan to ni awọn DSS pa ẹsọ alaabo ni Nkpor ipinlẹ Anambra ni ọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Kẹsan 2021''.
''Eyi si ni lati fi to araalu leti pe irọ gbaa lawọn ọrọ yi ati pe ko si idi kankan ti yoo mu wa pa onimọ iṣegun yi tabi awọn ẹsọ alaabo akẹgbẹ wa''.

Oríṣun àwòrán, CHIDIOGO AKUNYILI
Wọn fi kun UN pe awọn mọ pataki ẹmi eeyan ati pe awọn ni igbagbọ ninu titẹle ofin.
Bakan naa ni wọn ni ki araalu yago fun awọn to n gbe iroyin ẹlẹjẹ kaakiri lati fi si eeyan lọna.
Lọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Kẹsan ni awọn agbebọn pa Onimọ Chike to jẹ ọkọ ọjọgbọn Dora Akunyili to fi igba kan jẹ oludari ajọ to n mojuto oogun ati ilera NAFDAC.
Ni agbegbe Umuoji ni ijọba ibilẹ Idemili ni Anambra ni awọn ileeṣẹ iroyin ni iṣẹlẹ yi ti waye.
Eleyi si mu iriwisi ọtọọtọ waye tawọn kan si n gbe iroyin kaakiri lori opo ayelujara.
Ọga agba ọlọpaa ni Anambra kan si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye to si sọpe awọn yoo mu opin ba awọn iṣẹlẹ buruku to gbogo ni ipinlẹ naa.
Kini aarẹ Buhari sọ si iṣẹlẹ yi
Aarẹ Naijiria Muhammadu Buhari ti fi ẹdun ọkan rẹ hn lori iṣẹlẹ buruku ipaniyn Chike Akunyili yi.
Ninu atẹjade lati ọdọ oluranlọwọ patki rẹ Femi Adesina, aarẹ ni oun ba awọn mọlẹbi ati ọmọ kẹdun iku Dr Chike.
O ni oun ranti ibaṣepọ to wa nigba ti oun ba Dokita Akunyili ṣisẹ pọ ni PTF to fi kun pe
''Awọn ọmọ Naijiria ko ni gbagbe akikanju obinrin to jẹwọ ara rẹ gẹgẹ bi ọmọ Naijiria tọkantọkan''
O finu pawọn mọlẹbi pe awọn to hu iwa buruku yi ko ni lọ lai jiya ẹṣẹ wọn niwaju eeyan ati ẹlẹda.
Yàtọ̀ sí ọkọ Dora Akunyili, wo àwọn ibòmìí tí wọ́n tún ti pààyàn ní Anambra lọ́jọ́ kan nàá
Inu ibẹru-bojo ni awọn eniyan ipinlẹ Anambra ṣi wa lọwọlọwọ nitori iku Dokita Chike Akunyili, ọkọ oloogbe Dora Akunyili.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ṣe sọ, iku Dokita Akunyili nikan kọ lo waye nipinlẹ naa lọjọ Iṣẹgun.
Ọna marun-un ni itajẹ silẹ ti waye.
Akojọpọ awọn ipaniyan to waye ọhun rẹ e:
- Dokita Chike Akunyili, ni awọn agbebọn ti ẹnikẹni ko mọ yinbọn pa ni Umuoji, nijọba ibilẹ Idemili North nirọlẹ ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an. Eyi waye lasiko to n pada si Enugu lẹyin to kopa nibi eto kan ti wọn fi yẹ iyawo rẹ si nilu Anambra. Wọn pa awakọ rẹ naa, ati ọlọpaa to wa pẹlu rẹ.
- Awọn janduku kọlu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ni agọ wọn to wa ni Aguata Area Command ni nkan bi aago meji ọsan ọjọ Iṣẹgun bakan naa. Asiko ti awọn ọlọpaa naa n einkiri fun eto aabo ni opopona Ezinifite/Igboukwu ni wọn kọlu wọn, ti wọn si dana sun ọkọ wọn. Amọ, ko si ẹni to ku.
- Ni bi aago marun-un irọle ọjọ naa bakan naa, awọn agbebọn kọlu ẹnikan ni opopona Oko.
Wọn dana sun ọkọ rẹ, wsn si fi onitshun silẹ pẹlu ọgbẹ ibọn, ki wọn o to o salọ.
Awọn eeyan ri ẹni naa doola, wọn si gbe lọ sileewosan.
- Lọjọ yii kan naa, ni bi aago mẹrin irọle, awọn agbebọn kan gbiyanju lati gba ọkọ ayọkẹlẹ Lexus 350 lọwọ awakọ kan ni opopona Agulu, ti wọn si yinbọn mọ.
Botilẹ jẹ pe wọn pada salọ lai gbe ọkọ naa, ibọn ti wọn yin mọ ẹni naa gba ẹmi rẹ ki wọn o to o gbe de ileewosan.
- Ni bi aago marun-un ọjọ yii bakan naa, ni awọn agbebọn tun yinbọn pa Isipẹtọ ọlọpaa kan ni Nkpor Round-abaout, wọn tun bẹ ọkunrin kan lori.
Gbogbo ikọlu yii waye ṣaaju idibo gomina ipinlẹ Anambra, ti yoo waye ni ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla.
Gomina ipinlẹ Anambra, Willie Obiano ti bu ẹnu ẹtẹ lu iwa ipanle to n waye nipinlẹ naa lati ọjọ diẹ sẹyin.

Oríṣun àwòrán, ANAMBRA STATE GOvernMENT
O si ṣeleri ogun miliọnu Naira fun ẹnikẹni to ba ni aṣiri to le ṣe atọna fun bi ọwọ yoo ṣe tẹ awọn to n ṣe ikọlu nipinlẹ naa.
Ẹgbẹ́ IPOB ní òun kò lọ́wọ́ nínú ikú ọkọ Dora Akunyili, Chike
Ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹ-ede Biafra, IPOB, ti kede pe oun ko lọwọ ninu bi awọn agbebọn ṣe pa ọkọ alaga ajọ NAFDAC nigba kan, oloogbe Dora Akunyili, Chike Akunyili.
Ọjọru ni iroyin jade pe awọn agbebọn pa ọjọgbọn Akunyili, awakọ rẹ, ati ẹṣọ alaabo rẹ kan, lasiko to n rinrinajo lati ipinlẹ Anambra si Enugu.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ IPOB fi sita, ẹgbẹ naa sọ pe oun ko lọwọ si awọn ipaniyan to n waye lasiko yii nilẹ Biafra.
O ni "awọn oloṣelu kan lo n fi orukọ IPOB boju, lati ma a pa awọn alatako wọn".
"A ko ni ede aiyede kankan pẹlu Chike Akunyili, a ko si mọ ọ ri."
IPOB sọ pe ki gbogbo awọn to n fi orukọ ẹgbẹ naa boju ṣe iṣẹ ibi jawọ ninu iwa naa.
Wọn ṣapejuwe iku Ọjọgbọn Akunyili gẹgẹ bi ipaniyan oṣelu, eyi to n waye lọwọlọwọ nitori eto idibo gomina ipinlẹ Anambra to n bọ.
Bí àwọn agbébọn ṣe pa ọkọ mínísítà ètò ìròyìn tẹ́lẹ̀, Dora Akunyili
Awọ agbebọn kan ti yibọn pa dokita Chike Akunyili, to jẹ ọkọ minisita fun eto iroyin tẹlẹ, Ọjọgbọn Dora Akunyili.
Iroyin ni awọn agbebọn ọhun ṣekupa okunrin naa niulu Umuoji, to wa ni ijọba ibilẹ ariwa Idemili, ni ipinlẹ Anambra.
Ẹnikan to sumọ idilẹ oloogbe naa ṣalaye fun awọn akọroyin pe oloogbe ọhun ṣi wa nibi ipade awọn akẹkọjade faisiti ijọba apapọ to wa ni Nsuka, UNN, nibi ti wọn ti ṣe ayẹsi fun un.
- A óò fi imú gbogbo àwọn tó ṣekúpa ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Eko dárin - Sanwo-Olu
- 'Àyẹ̀wò ìdákọ́ńkọ́ mi gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nípa ìhùwàsí ọmọde fihàn pé Baba Ijesha fọwọ́ kan ọmọ Princess lọ́nà tí kò tọ́'
- 'Kàǹkàn ìbílẹ̀, òògùn, àwọ̀tẹ́lẹ̀ àti fóònù lá bá lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú obìnrin tí wọ́n dédé jù sí àdúgbò wa l'Akure'
- Ayé ò! Báyìí ní ọwọ́ FBI ṣé tún tẹ àwọn gbájúẹ̀ ọmọ Nàìjíríà 11 ní Texas
- Ìpanu ''small chops'' ló mú kí sọ́jà da omi ìdọ̀tí lé mi lórí - Corper Fidelia
- Adigunjalè kọlu báǹkì ní Iragbiji l'Osun, ìlú dàrú
- Mọ̀ nípa àìsàn tó ń mú ǹkan ọmọkùnrin lè gìdìgbà láì rọlẹ̀
Ẹni naa sọ pe "Mo ṣi wa pẹlu rẹ lanaa ni gbọgan Sheraton to wa nile ijọsin All Saints Cathedral niluu Onitsha."
"Nibẹ ni a ti ṣe ipade awọn akẹkọjade faisiti ijọba apapọ to wa ni Nsuka nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti ṣe ayẹsi fun. un"
Ẹni naa ṣalaye pe oloogbe ọhun sọrọ daadaa nipa iyawo rẹ to jẹ minisita nigba kan ri, o si fi ẹbun owo 500,000 naira ta ẹgbẹ awọn akẹkọjade lọrẹ.
O ni "Koda, oun ati ọmọ rẹ okunrin ti orukọ rẹ n jẹ Obum ni wọn jọjọ wa nibi ipade naa."
"A sin awọn mejeji lọ sidi ọkọ wọn, baba ati ọmọ naa si di mọ ara wọn ki awọn mejeji to pinya lọ sidi ọkọ wọn."
Ẹwẹ, ẹlomiran to sunmọ ẹbi ọloogbe naa ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC.
Ẹni naa ni inu ibanujẹ nla ni awọn ẹbi oloogbe naa wa lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.
















