Osun Strike: Gbèdéke ọjọ́ méje ni àwọn olùkọ́ ilé ẹkọ́ gíga fún ìjọba

O da bi ẹni pe gbẹgẹdẹ fẹ gbina laarin awọn olukọni kaakiri awọn ileewe giga mẹrẹẹrin to wa ni ipinlẹ Ọṣun.
Ko si idi meji ju bi awọn olukọni naa ti ṣe faake kọri pe iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ lawọn yoo fi yanju ọrọ ilaji owo osu ọdun meji ati aabọ ti ijọba ipinlẹ Ọṣun jẹ wọn.
Awọn olukọni naa, labẹ aṣia ẹgbẹ olukọni ileewe giga nipinlẹ Ọṣun, CASUOSTI, wa fun ijọba ni gbedeke ọjọ meje lati pe awọn olukọni naa si ajọ ijiroro, lori ọrọ naa bibẹẹkọ awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi ni pẹrẹu.
Adele alaga ẹgbẹ awọn olukọ ileewe giga naa, Comrade Oluṣẹgun Lana ṣalaye lẹyin ipade ẹgbẹ naa, to waye lọgba ileewe ẹkọṣẹ olukọni agba to wa nilu Ilesa pe, gbogbo igba ni ijọba n kuna lati ṣika adehun to ṣe pẹlu ẹgbẹ naa lati igba ti ijọba ana ti wa nipo.
Comrade Lana mẹnuba diẹ lara awọn ẹhonu awọn olukọni ileewe giga naa, eyi to ni o kun aisan ajẹẹlẹ abọ owo oṣu wọn fun ọgbọn oṣu, ktitapa si ofin ẹdawo ifẹyinti, ati bi ijọba ko tii ṣe san owo to rọ mọ eto igbega oṣiṣẹ laarin ọdun 2014 si 2018.
Bakan naa lo ni ọrọ yiyọ ida kan abọ 1.5% ninu owo oṣu awọn oṣiṣẹ naa fun eto adojutofo ilera NHIS, ṣi n ṣe ajoji si wọn.
Amọṣa, o ni awọn olukọ naa fẹ jiroro pẹlu ijọba, iyẹn bi ijọba ba ṣetan fun ifikunlukun to dan mọran.
Awọn ileewe giga ti ọrọ naa kan, ni ileewe ẹkọṣẹ olukọni agba to wa nilu Ila Ọrangun, ileewe ẹkọṣẹ olukọni agba to wa nilu Ilesa, ileewe gbogboniṣe poly ti ilu Iree ati ileewe imọ ẹrọ OSCOTECH, Esa oke.















