JAMB Result 2019: 34,120 akẹ́ẹ̀kọ́ ni kò ní èsì ìdańwò JAMB

Oríṣun àwòrán, JAMB
Ajọ to n bojuto idanwo asewọle si ile iwe giga, JAMB ti ni akẹẹkọ ọdọmọkunrin ọdun mẹẹdọgun, Elene Franklin lo gba maaki to pọju lọ ninu esi idanwo JAMB.
Adari Ajọ JAMB, Ishaq Oloyede sọ eyi lasiko to n kede wi pe awọn ti fi esi idanwo JAMB sita fun awọn akẹẹkọ lati mọ bi wọn se yege si ninu idanwo naa.
Oloyede ni Franklin gba iye maaki aadọtalelẹlọọdurundinmeji(348) ninu erinwo(400).
o wi pe akẹẹkọ to le ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn (34,120) ni awọn ti awọn ko ni fi esi idanwo wọn sita.
Oloyede ni akẹẹkọ to le ni miliọnu (1,792,719) ni wọn yoo ri esi idanwo gba ninu iye awọn to se idanwo naa (1,886,508).
Amọ, O ni gbogbo ojude ti wọn ti se magomago ninu idanwo naa ni awon ti ti pa, ti ko si ni si idanwo ni ojude naa mọ.
Adari Ajọ JAMB naa wa parọwa si awọn akẹẹkọ naa lati wo esi idanwo wọn ti wọn ba ti tẹ atẹjisẹ 'RESULT' si '55019' lori ẹrọ ilewọ wọn, lai lọ si ori ẹrọ ayelujara lati lọ wo o.









