Nigeria Police: Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fẹ́ gba ọ̀pọ̀ kọ́ńsítébù láti ranwọ́ lórí ètò ààbò

Abubakar Mohammed Adamu

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force

Àkọlé àwòrán, Eto aabo Naijiria

Lara akitiyan rẹ lati ri wi pe eto aabo gbopọn si lorilẹede Naijiria, ile iṣẹ ọlọpaa ti ṣetan lati gba ọpọlọpọ kọnsitebu ti yoo maa ṣiṣẹ pẹlu awọn agbofinro lawujọ

Alukoro fun ile iṣẹ ọlọpaa Frank Mba ṣalaye pe awọn kọnsitebu yii yoo maa ṣeranwọ fawọn ọlọpaa ṣugbọn wọn ko ni lanfani lati gbebọn.

Igbaniṣiṣẹ awọn kọnsitebu ti ile iṣẹ ọlọpaa yoo kede rẹ laipẹ niroyin sọ pe ijọba apapọ gan an fọwọ si.

Bakan naa, iroyin tun sọ pe awọn gomina gan an ko sai fọwọ si igbesẹ ile iṣẹ ọlọpaa ọhun.

Agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa to fọrọ naa lede sọ pe awọn eeyan ti ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ọmọ ọdun mọkanlelogun si aadọta ọdun ni ile iṣẹ ọlọpaa fẹ gba fun iṣẹ ọhun.

A tun gbọ pe ile iṣẹ ọlọpaa n gbero lati gba awọn ọmọluabi eeyan bi alufa ijọ, imaamu, agbẹjọro, oniroyin, olukọ ati awọn ọdọ fun iṣẹ naa.