EFCC: Nítorí ẹ̀sùn 419 laaṣe mú Naira Mailey àti ikọ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, EFCC
Ajo to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC ti fi lede wi pe lootọ ni awọn fi panpẹ ofin mu olorin takasufe, Afeez Fashola, ti awọn eniyan m si Naira Mailey ati ikọ rẹ.
Adele Agbẹnusọ fun ajọ EFCC, Tony Orilade ni ẹsun jibiti, ole ati lilo ẹrọ ayelujara lati fi gba owo lọwọ awọn eniyan ni awọn fi sun un.
Orilade fikun ọrọ rẹ pe, Mailey nikan kọ ni awọn fi panpẹ ọba mu, awọn miiran to wa pẹlu rẹ naa wa lara awọn ti awọn mu.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ni ọse yii ni gbajugbaja olorin Ruggedman fi fidio sita pe onijibiti to n se yahoo yahoo ni Naira Mailey.
Amọ Mailey ninu awọn orin rẹ tuntun fi Ruggedman ṣe yẹyẹ lori ọrọ naa.









