New Emirates: Ilé ẹjọ́ dá Gómìnà Ganduje dúró yíyan àwọn Emir tuntun ní Kano

Oríṣun àwòrán, Facebook/Abdullahi Ganduje
Ile ẹjọ giga kan niluu Kano ti paṣẹ fun gomina Abdullahi Ganduje lati sẹ mẹdọ lori igbesẹ rẹ lati yan awọn ọba miiran yatọ si Emir ilu kano Sanusi Lamido Sanusi.
L'Ọjọru ọsẹ yii ni gomina Ganduje buwọlu aba ti yoo jẹki Sanusi lagbara lori ijọba ibilẹ mẹwaa pere ninu mẹrinlelogoji to wa nipinlẹ Kano.
Ṣugbọn adajọ Nasiru Saminu sọ pe ki Gomina Ganduje k'ọwọ ọmọ bọ aṣọ na lẹyin ti awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kano meji, Rabi'u Saleh Gwarzo ati Babangida Yusuf Sulaiman gbe Ganduje lọ sile ẹjọ lori igbesẹ rẹ.
Awọn aṣofin naa ni igbesẹ lati yan awọn Emir miiran nipinlẹ Kano lodi si ofin ipinlẹ naa.
Adajọ Saminu fidi rẹ mulẹ niu idajọ rẹ pe ki o digba ti igbẹjọ ba pari ki gomina Ganduje to lo gbe igbesẹ kan tabi omiran lori ọrọ Emir ilu Kano.
Ọjọ Abamẹta ni ijọba n gbero tẹlẹ lati fun awọn Emir tuntun to ba yan ni iwe ẹri tẹlẹ ki ile ẹjọ to daa duro.










