9th Assembly: Dogara kìlọ̀ fáwọn ẹgbẹ́ òṣèlú láti má dásí yìyan olórí ilé

Yakubu Dogara

Oríṣun àwòrán, @YakubuDogara

Adari ile aṣoju aṣofin l'Abuja, Yakubu Dogara ti rọ awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu lati jẹ ki awọn ọmọ ile aṣofin mejeeji yan awọn olori wọn fun ra wọn.

Dogara ni o ti han gbabgba pe, awọn aṣofin korira ki ẹgbẹ oṣelu kan yan awọn olori fun wọn ninu ile.

Nigba ti o n sọrọ nibi eto ilanilọyẹ fun awọn ọmọ ile tuntun niluu Abuja, Dogara sọ fawọn eekan nilu ẹgbẹ oṣelu, lati jẹ ki awọn ọmọ aṣofin mọ igbesẹ wọn lori ati yan olori.

Dogara sọ pe oun gan ko le sọ fun awọn ọmọ ile lati yan ẹnikan, bi ko ṣe ki wọn dibo yan ẹni to ba wu wọn.

Dogara fikun ọrọ rẹ pe, awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu gbọdọ rii pe wọn ko da ile aṣofin mejeeji pada sẹyin nipa fifa olori kalẹ fun wọn.

Àkọlé fídíò, Mò ń fi lẹ̀kẹ̀ ya àwọnran láti jèrè ǹkan méjì - Olaniyi Olaniyan

O wa rọ awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin lati wo awọn eto ti awọn oludije fun ipo olori ni fun wọn, ki wọn si dibo fun ẹni to wu wọn.