Election Update 2019: Àwọn olórí orílẹ̀èdè lágbàyéé ń kí Buhari kú oríire

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Minisita fun ọrọ Afrika labẹ ijọba Ilẹ Gẹẹsi Harriet Baldwin ti ki Aarẹ Muhammadu Buhari ku ori ire, o si ke pe awọn ti esi idibo naa ko ba tẹ lọrun lati gbe igbesẹ to yẹ lọna alaafia.

Baldwin ni ijọba Ilẹ Gẹẹsi lero wipe esi idibo naa yoo ba awọn ọmọ Naijiria lara mu. O ni esi idibo ti INEC kede ba eyi ti awọn ajọ alamojuto ko jọ.

Wọn tun ba awọn ti o ẹmi won ba idibo naa lọ kẹdun, ti wọn si sọ wipe ko yẹ ki ẹnikẹni ku nibi to ti n gbẹ igbesẹ fun ijọba awa arawa.

Awọn asaaju orilẹede ti n fi isẹ ikini wọn ransẹ si aarẹ Muhammadu Buhari to jawe olubori lati lọ fun saa keji ninu eto idibo to kọja.

Atẹjade kan ti oludamọran si aarẹ Buhari feto iroyin, Fẹmi Adesina fisita ni aarẹ orilẹede Ghana, Nana Koffi Addo, Mahamadou Issoufou tilẹ Niger ati Macky Sall ti orilẹede Senegal ti fi fi isk ikinni ku oriire ransẹ si aarẹ Muhammadu Buhair.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi atẹjade naa ti wi, awọn asaaju orilẹ ede naa ni aarẹ Buhari moke ninu eto idibo naa lati lọ fun saa keji, nitori igbẹkẹle ati igboya tawọn ọmọ Naijiria ni ninu rẹ.

Wọn wa gbadura fun aarẹ Buhari pe yoo se aseye ti alakan n se epo ni saa keji to gba yii.