Ekiti: Awọn ọ̀dọ́ 2000 yóò gba iṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn àgbàlagbà tó fẹ̀yìntì

Oríṣun àwòrán, @ekitistategov
Ko din ni awọn ọdọ ẹgbẹrun mejidinlaadọta (48,000) ti wọn ti gba fọọmu igbanisiṣẹ ti wọn si tun ti joko ṣe idanwo igbanisiṣẹ to n lọ lọwọ bayii nipinlẹ Ekiti.
Pabambari ibẹ ni pe aaye iṣẹ fun ẹgbẹrun meji eeyan lo wa nilẹ nipinlẹ naa.
Bi a o ti wa ṣee ti ọdọ ẹgbẹrun mejidinlaadọta (48,000) yoo ṣe gba iṣẹ ẹgbẹrun meji (2000) ni idamu to ba awọn alaṣẹ igbanisiẹ naa bayii nipinlẹ Ekiti.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Atẹjade kan lati ọdọ olori ẹka oṣiṣẹ ọba nipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Olugbenga Faṣeluka fi sita ṣalaye pe eredi eto igbanisiṣẹ naa ni lati di awọn aaye to ṣi silẹ lẹka iṣẹ ijọba nipinlẹ naa.
O ni alafo ti o waye lẹyin ti awọn oṣiṣẹ ti ijọba ipinlẹ Ondo atijọ labẹ Oloye Adekunle Ajaṣin laarin ọdun 1881 si 1982 gba sisẹ fi silẹ lẹyin ti wọn fẹyinti lọgọọrọ lo faa.bi o tilẹ jẹ pe awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ti n pariwo pe ofutufẹtẹ lasan ni eto ọhun, ṣugbọn olori ẹka oṣiṣẹ ọba nipinlẹ ọhun ni awọn ẹka ti o ṣe koko ni wọn fẹ gba awọn eeyan naa si.









