Òsìsẹ́ ìjọba: Ọmọ títọ́ kò rọrùn rárá, ọdún kan kò pọ̀jù!

Obinrin to n fomo loyan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, 'Igbesẹ̀ to dara ni ijọba gbe, amọ pe obinrin nilo ọdun kan lati faramọ ọmọ ti wọn sẹsẹ bi’

Awọn ọmọ Naijiria ti fesi lori igbese ijọba apapọ lati fi osu kan kun ọjọ isinmi awọn osisẹ'binrin to ba sẹsẹ bimọ, eleyii to sun un lati osu mẹta si mẹrin.

Minisita fọrọ oṣiṣẹ ati igbanisisẹ lorilẹ-ede Naijiria, Sẹnatọ Chris Ngige, lo sọ ọrọ yii nibi ipade ‘International Labour Confedence’ to n lọ lọwọ ni Geneva, lorilẹ-ede Swtizerland.

Ngige fikun pe ijọba apapọ ti f'ofin de isẹ awọn abiyamọ, ati pe wọn ko gbọdọ yọ ẹnikẹni ni isẹ nitori o lọ fun isinmi lẹyin ibimọ.

Abilekọ Adeọla Akọgun to jẹ osisẹ ijọba ba BBC Yorùbá sọrọ lori igbese naa sọ pe ‘igbesẹ̀ to dara ni ijọba gbe, amọ obinrin nilo ọdun kan lati faramọ ọmọ ti wọn sẹsẹ bi naa ki ibasepo to dan mọran le wa laarin wọn'.

Bakan naa, Abilekọ Funke Olutuyi, ba BBC Yorùbá sọrọ gẹgẹbi onisẹ ọwọ, pe, o pọn dandan lati fi osu mẹfa silẹ lati fun ọmọ ni ọyan lai fi ounjẹ la a, ki ara ọmọ o ba le ji pepe

Àkọlé fídíò, ‘A nílò ọdún kan láti sinmi lẹ́yìn ìbímọ’ - Òsìsẹ́ ìjọba

Njẹ ọkunrin nilo isinmi nigba ti iyawọ wọn ba sẹsẹ bi ọmọ?

Laipe yii ni ijọba fagile erongba awọn ọkunrin lati máa gba isinmi osu kan lẹyin ti iyawo wọn ba bimọ, ki wọn ba le se itọju wọn bo ṣe to ati bo ti yẹ.

Amọ, Ọmọwe Micheal Afolayan nigba to n ba BBC Yorùbá sọrọ lori koko yii pe, ọkunrin kò nilo isinmi lasiko ti iyawo wọn ba sẹsẹ bimọ, nitori obinrin lo máa n se isẹ inu ile.

Dokita Afolayan wa kan sara si ijọba apapọ fun igbese naa, o si rọ awọn ọkunrin lati tẹpa mọ isẹ nitori ọwọ to ba dilẹ ni esu máa n lo.

Àkọlé fídíò, Njẹ ọkunrin nilo isinmi nigba ti iyawọ wọn ba sẹsẹ bi ọmọ?

Ipa ti isinmi osu mẹrin yoo ko lori eto ọrọ aje

Ajafẹtọ ọmọ eniyan lori ọrọ igbanisisẹ ati agbẹjọro, Babatunde Ogala, nigba to n fi ero rẹ han lori igbese ijọba apapọ naa sọ pe, isinmi osu mẹrin fun awọn osisẹ obinrin lẹyin ibimọ yoo mu ibugbooro ba eto ọrọ aje orilẹ-ede Naijiria nitori awọn obinrin yoo pa ọkan wọn papọ si ọna kan nigba ti wọn ba n tọ ọmọ lọwọ.

Àkọlé fídíò, Ipa ti isinmi osu mẹrin yoo ko lori eto ọrọ aje

Bakan naa o fikun wi pe, ọjọ iwaju awọn ọmọ ti wọ̀n sẹsẹ bi naa se koko, nitori itọju ti wọn ba fun wọn ni kekere ni yoo mu wọn dagba bo se ye, ati lati gbe orilẹ-ede wọn ga.