Ọdẹ́gbàmí: Púpọ eléré ìdárayá ló ti gba ẹ̀bùn wọn lọ́wọ́ ìjọba

Ṣẹgun Ọdẹgbami

Oríṣun àwòrán, guardian.ng

Àkọlé àwòrán, Lẹyin ọdun mejilelogun, olukọni ikọ agbabọọlu Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Bonfere Jo, ṣẹṣẹ gba kọkọrọ ile ti wọ́n fun un

Gbajugbaja agbabọọlu orilẹ-ede Naijiria nigbakan ri, Ṣẹgun Ọdẹgbami, ti sọ wi pe pupọ awọn elere idaraya ti ijọba pinnu ati fun ni awọn ẹbun ni wọn ti ń gba irufẹ awọn ẹbun bẹẹ.

Ṣẹgun Ọdẹgbami ṣalaye fun BBC Yoruba pe, lootọ ni ijọba ṣe ileri ẹbun fun awọn elere idaraya, paapaa julọ ti bọọlu aláfẹsẹgba lọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Ṣugbọn o ni ninu iwoye oun, pupọ awọn ẹbun wọnyii lo ti de ọwọ awọn elere idaraya bẹẹ.

Ni ọjọ Iṣẹgun ni ijọba apapọ nipasẹ minisita fun iṣẹ akanṣe, ipese oun amuṣagbara ati ọrọ ileegbe, Babatunde Faṣọla, fun akọnimọọgba ikọ̀ agbabọọlu 'Dream Team' to gba goolu ni idije Olympics l'ọdun 1996, Bonfere Jo, ni kọkọrọ ile ti ijọba ìgbà naa ṣeleri fun un gẹgẹ bii ẹbun nigba naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amin iyasọtọ kan

Amọṣa, ninu ọrọ rẹ, Ọgbẹni Ọdẹgbami ni oniruuru nkan lo ṣokunfa bi ọrọ ṣe lọ pẹlu awọn ẹbun ti wọn fun awọn agbabọọlu to pegede lọdun 1996 pupọ eyi to ni kii ṣe ẹbi ijọba.

"Lori ọrọ Jo Bonfere ti ẹ n sọ yii, mi o fi bẹẹ mọ. Ohun ti mo mọ ni pe pupọ awọn ti ọrọ kan ni wọn ti gba ẹbun ile tiwọn lọwọ ijọba. Mi o mọ idi ti tiẹ fi ri bẹẹ.

Oniruuru iṣoro lo koju ipese ẹbun ile naa nigbanaa nitori ọtọọtọ ni ibi ti awọn ti ọrọ kan ti fẹ ki ile wọn wa ki o to di pe olori iṣejọba nigbanaa dagbere faye."

O ni ko si ẹni to ṣe ileri ohunkohun fun awọn agbabọọlu saa rẹ ni ọdun 1980, ṣugbọn gbogbo wọn ni wọn ti gba ẹbun ile ti ijọba igba naa fun wọn.

"Ni ọdun 1977, 1978 ati 1980 ko si ẹni to ṣeleri ohunkohun fun awọn elere idaraya o, ẹbun gbogbo ti wọn fun ikọ naa ni wọn ti gba."