UEFA: Buffon yóò pàdánù ìdíje mẹ́ta nítorí ìwà ọ̀yájú

Rẹfirí Michael Oliver

Oríṣun àwòrán, Empics

Àkọlé àwòrán, Aṣọ́lé Gianluigi Buffon ṣe àpèjúwe rẹfiirí Michael Oliver gẹ́gẹ́ bí ẹnití àyà rẹ̀ kún fún ìdọ̀tí dípò ọkàn.

Agba ọjẹ aṣọle tẹ́lẹ̀ fún Juventus, Gianluigi Buffon, ni ajọ UEFA ti fote le bayi pe, ko ni kopa ninu ifẹsẹwónsẹ mẹta nítorí ọrọ to sọ si rẹfiri Michael Oliver.

Adarí ìdíje náà, táa tún mọ sí Rẹfiri, le Buffon jade lẹyin igba to fun ikọ alatako Real Madrid ni pẹnariti ninu ipele komẹsẹ-ọ-yọ onikọ mejọ, ninu idije Champions League loṣu Kẹrin.

Aṣọle tẹ́lẹ̀ fún Juventus, Gianluigi Buffon

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Buffon ṣe apejuwe Oliver gẹgẹ bi ẹniti aya rẹ kun fun idọti dipo ọkàn.

Lẹyin idije naa, Buffon ṣe apejuwe Oliver gẹgẹ bi ẹniti aya rẹ kun fun idọti dipo ọkàn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Buffon tun sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan pe, oun ṣetan lati sọrọ kan naa pẹlu ede miran.

Buffon ṣoju ikọ Juventus fun igba ikẹyin, ninu oṣu Karun un, lẹyin igba to ti gba bọọlu fun ikọ naa fun ọdun mẹtadinlogun.