Íyanṣẹ́lòdì Johesu: ǹkan ń bàjẹ́ síi ni fún àwọn ará ìlú

Aworan awọn alaisan ni ile iwosan
Àkọlé àwòrán, Àwọn aláìsàn n dúró dé àwọn òṣìṣẹ́ ìlera lati wa tọjú wọn

Ọrọ iyanṣelodi láwọn ilé ìwòsan káàkiri orílè-èdè Nàìjíríà ti mu ki ìnira túbọ̀ peléke síi fún àwọn ará ìlú-ati awọn Dókítà.

Láwọn ilé ìwòsàn ti ìkọ BBC ṣe àbẹwò sí, awọn akẹkọọ dókítà ni wọn n gbé ìgbá, gbé àwo láti ríi pé àwọn aláìsàn ri itọju.

Dokita kan to bá BBC sọrọ ní "iṣẹ yìí tojú súmi. Ẹ wo bi awọn aláìsàn ṣe kun le lọrùn èmí nikan"

Amin iyasọtọ kan
Aworan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dókítà to n tọjú àwọn aláìsàn.
Àkọlé àwòrán, Awọn akẹ́kọ̀ọ́ dókítà la ri tí wọn n tọjú àwọn aláìsàn ni LASUTH

Nile ìwòsan ikọni ti fafiti ìpínlè Eko, LASU, ni Ikeja, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dókítà la ri tí wọn n tọjú àwọn aláìsàn.

Won ní iṣẹ wàhálà ni ṣugbọn ''o di dandan láti ṣe.''

Ọkan nínú wọn ni "a ko gba aláìsàn tuntun mọ. Àwọn tó tí wà nílé tẹlé nikan ní a ń tọjú"

Aworan awọn akẹ́kọ̀ọ́ dókítà LASUTH
Àkọlé àwòrán, Awọn akẹ́kọ̀ọ́ dókítà LASUTH

Bákan náà ni ọrọ ṣe rí ní ilé ìwòsan ìjọba tí o wà ní Ifako Ijaiye.

N'isẹ ní àwọn aláìsàn àti awọn dókítà n ke ìnira lori bi ko ṣe sí àwọn òṣìṣẹ́ ìlera nílẹ̀.

Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ní ilé ìwòsan ìjọba ìpínlè àti ìjọba ìbílẹ jakejado Naijirià darapọ̀ mọ́ iyanṣẹlodi labẹ àsìá ẹgbẹ oṣiṣẹ Johesu lojooru.

Ninu atejade ti awọn olórí ẹgbẹ náà fi sita, wọn ni igbésẹ náà wáyé láti mú kí ìjọba gbarata lórí iyanṣelodi ti àwọn ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ láti nnkan bíi ọsẹ mẹta sẹyìn

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: