Ibugbamu afẹfẹ gaasi meji pa ọpọ eniyan nipinlẹ Eko
Ijamba afẹfẹ idana gaasi miran tun ti waye lagbegbe Badagry nipinlẹ Eko, eleyi to mu ọpọ ẹmi lọ.
Ijamba ọsẹ afẹfẹ idana gaasi naa waye ni sọọbu ti wọn ti nta eroja idana ọhun ni opopona Iluda, Ajara Vetho n'ijọba ibilẹ Badagry.

Oríṣun àwòrán, AFOLABI AIGORO
Awọn ti isẹlẹ naa soju wọn ni bi ooru se mu awọn agolo afẹfẹ idana naa ni amuju lo sokunfa ibugbamu naa.
Ọga agba ileesẹ panapana ipinlẹ Eko, ọgbẹni Rasaq Fadipẹ to fi idi isẹlẹ yii mulẹ salaye fun BBC Yoruba ni kete ti wọn fi isẹlẹ ọhun to awọn panapana leti ni wọn ti kanlu agbami isẹ lati pa ina naa.
Sugbọn, ọgbẹni fadipẹ kọ lati sọrọ lori iye awọn eniyan to ku ninu isẹlẹ naa ayafi ti o ba ri ababọ awọn osisẹ ileesẹ naa to se iwadi lori rẹ.

Oríṣun àwòrán, AFOLABI AIGORO
Ọgbẹni Afọlabi Aigoro ti ọrọ naa se oju rẹ fi to ileesẹ BBC Yoruba leti wipe awọn agolo afẹfẹ idana gaasi ti awọn ajorinmọrin kan nlo lagbegbe naa lo fa ibugbamu ọhun to si se iku pa ọpọlọpọ to nkọja lọ.
Eyi ni gba keji laarin wakati diẹ sirawọn nilu Eko lọjọ aje tii irufẹ isẹlẹ ijamba ibugbamu afẹfẹ idana gaasi.
Akọkọ ti waye ni agbegbe Magodo nileesẹ ti wọn ti nta afẹfẹ idana naa lagbegbe ọhun.

Bi a ko ba gbagbe, isẹlẹ ibugbamu afẹfẹ idana gaasi kan ti waye ni kutu owurọ ọjọ aje yii kan naa ni agbegbe Magodo nibi ti eeyan meji ti se alaisi.
Oludari Igbimọ to nrisi isẹlẹ pajawiri ni ipinle Eko (LASEMA), ti fi idi rẹ mulẹ fun ikọ iroyin BBC pe, o kere tan, eniyan meji ti di oloogbe ti awọn mẹjọ miran farapa pupọ ninu ijamba ina gaasi to sẹlẹ ni owurọ yi lagbegbe Magodo nilu Eko.
Ile-iṣẹ naa sọ pe, awọn agba afẹfẹ gaasi nla mẹta ati ọkọ agbepo kan, to wa ni ibudo itaja gaasi "Second Coming Oil & Gas Nigeria Limited" lo gbana, ti awọn nkan miran si ran ina yi lọwọ ninu ibudo naa.

Biotilẹjẹpe awọn eeyan ti isẹlẹ naa soju wọn jẹri pe awọn osise ibudo itaja gaasi naa se akiyesi wipe, gaasi naa njo laaro kutukutu, ti wọn si pe akiyesi ajọ to n seto pajawiri ati awọn panapana si isẹlẹ naa.
Wọn salaye wipe, ijamba ina burẹkẹ lojiji, to si gba gbogbo ibudo naa kan.
Oludari ajọ to n pese nkan pajawiri nipinle Eko, ọgbẹni Adesina Tiamiyu fikun pe, awọn ti pa ina naa, atipe iwadi ti nlọ lori isẹlẹ iwadi ohun to fa ijamba yi , lati lee dẹkun irufẹ isẹlẹ bayi nilu Eko.

Bakanna, ọga agba fun ileesẹ panapana nipinlẹ Eko, ọgbẹni Radiq Fadipe fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, o sọ pe, ọkan lara awọ̀n eeyan to kọkọ foju se mẹrin ijamba ina yi, to tun jẹ ọkan lara awọn osisẹ panapana lo lugbadi ina yi, o si ti ngba itọju lọwọlọwọ nile iwosan.
Biotilẹjẹpe awọn eeyan ti isẹlẹ naa soju wọn jẹri pe awọn osise ibudo itaja gaasi naa se akiyesi wipe, gaasi naa njo laaro kutukutu, ti wọn si pe akiyesi ajọ to n seto pajawiri ati awọn panapana si isẹlẹ naa. Wọn salaye wipe, amọ ijamba ina burẹkẹ lojiji, to si gba gbogbo ibudo naa kan.
Oludari ajọ to n pese nkan pajawiri nipinle Eko, ọgbẹni Adesina Tiamiyu fikun pe, awn ti gbakoso isẹlẹ naa, tawọn yoo si se iwadi ohun to fa ijamba yi , lati lee dẹkun irufẹ isẹlẹ bayi nilu Eko.












