Johesu: Òsìsẹ́ ìlera ti bẹrẹ iyanselodi

Aworan ile iwosan

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Iyansẹlodi lẹka ilera orileede Naijiria ki se ohun tuntun mọ

Àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera lorilede Naijiria, labẹ àsìá ẹgbẹ apapo awọn oṣiṣẹ ilera Johesu ti bẹrẹ iyansẹlodi loni.

Awọn oṣiṣẹ náà, paapa julo, àwọn tó n ṣiṣe ni awọn ile ìwòsan ìjọba àpapọ, ni yóò kọ̀kọ̀ bẹrẹ iyansẹlodi náà.

Atẹjade kan lati ọdọ igbákejì alága ẹgbẹ́ náà, Ogbonna Chimela ní, ti ìjọba ba je ki iyanselodi náà tẹsiwaju lẹyìn ọsẹ méjì, gbogbo awọn ile iwosan ìjọba ìpínlè àti tìbílẹ̀ ni yóò darapo mo iyanselodi náà.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amin iyasọtọ kan

Eyi kìí ṣe iyanselodi àkọkọ

Losu kẹsán ọdún tó lọ, ní iyanselodi kàn wáyé lórí àfikún owó oṣù, ajemọnu, igbega ati àwọn ẹtọ míràn fún àwọn osíṣe ìlera lorileede Naijiria.

Idasẹsile náà mú ìnira ba opo aláìsàn ṣugbọn lójó keje idasẹsile náà, wọn yanjú òrò ọ̀hún ní tunbi n nubi pẹlu ijọba.

Ijọba ko ka wa kun

Jack Lampang, to je alamojuto eto iroyin fun Johesu ni, ko si nnkan ti ẹgbẹ naa n beere fun, bi ko se ki ijọba fun awọn ni ẹto awon.

Alaisan kan to sun lori ibusun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Johesu ni oun mo wi pe ara yoo ni awọn ara ilu lori idasẹsile naa

''Awọn Dokita nikan kọ ni osise ilera to wa ni Naijiria. Lai pe yi ni ijọba sika adehun ti wọn se pẹlu awọn onimo isegun sugbọn ti ọrọ ba kan ti awa osise to ku, awawi ni wọn ma n so''

Jack ni awọn ti fun ijoba ni anfaani lopo igba lati yanju oro naa lai se pe awọn dase sile.

"A mo wi pe ara yoo ni awọn ara ilu lori idasẹsile nitori re ni alaga wa fi ni ki idasesile naa mo ni awọn ile iwosan ijọba apapo nikan bayi. Bi won ba ko lati sika adẹhun ti wọn se pẹlu wa, awọn ile iwosan ìjọba ìpínlè àti ìbílẹ̀ naa yóò darapo mọ iyansẹlodi náà. ''

BBC Yoruba gbiyanju lati ba Minista feto ilera lorileede Naijiria sọrọ sugbọn ẹni to gbe ipe rẹ ni o wa ninu ipade kan.

Aworan ile ìwòsan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn Dokita ati awọn osise ilera miran ko gba dede iye owo kannáà.

Ìjà orogún awọn dokita àti oṣiṣẹ ilera.

Losu kẹwa ọdún tó kọjá, awọn Dókítà orileede Naijiria, labẹ àsìá ẹgbẹ onimo isegun sapèjúwe ẹgbẹ àwọn oṣiṣẹ ilera Johesu gẹgẹ bii "ajo ti ko bofinmu".

Wọn ni ọpọ òun ti Johesu n béèrè fún ko bójú mu.

Ọjọgbọn Mike Ogrima, to jẹ Ààrẹ ẹgbẹ onimo ìṣegun ni '' A lòdì sí kí àwọn Dókítà àti oṣiṣẹ ilera jijo ma gba iye owo kannáà. Johesu n bèèrè fún ìbádọ́gba owo láàrin àwọn oṣiṣẹ ilera to ku ati awon Dókítà.''