Ìjínigbé Nàìjíríà: Agbébọn pa ọlọ́pàá, ó jí ọmọ Germany gbé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn agbébọn ti pa ọlọ́pàá kan, wọ́n sì jí ọmọ orílẹ̀edè Germany kan gbé ní ìpínlẹ̀ Kano ní ìhà àríwá orílẹ̀edè Nàìjíríà.
Ìsẹ̀lẹ̀ yìí wáyé lọ́jọ́ ajé.
Nínú àtẹ̀jáde kan tó wá láti ilé isẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kano, wọ́n fi àìdunnú hàn sí ìsẹ̀lẹ̀ ọ̀hún gẹ́gẹ́ bí wọ́n se kéde f'árá ìlú.
Ìsẹ̀lẹ̀ abúrú yìí wáyé lọ́jọ́ kẹrìndínlógún osù kẹrin ọdún 2018 ní òpópónà Sabon Titi Madobi, ìlú Kano níbi tí ikọ̀ adigunjalè ẹlẹ́ni márùún nínú ọkọ̀, tú kẹ̀kẹ́ ìbọn sórí ọkọ̀ kan tó ńgbé àwọn òsìsẹ́ ilé isẹ́ agbasẹ́se Dantata & Sawoe lọ sí ibi isẹ́ àgbàse wọn.
Àwọn akọluni náà pa sájẹ̀ntì ọlọ́pàá kan tí ó wà lẹ́nu isẹ́ àkànse ìpèsè ààbò, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n jí ọ̀gbẹ́ni Michael Cremza, ọmọ ìlú German,y tó ń sisẹ́ darapọ̀ mọ́ ilé isẹ́ náà gbé.
Ẹnikẹ́ni tó bá ní ìròyìn nípa àwọnajínígbé yìí leè kàn sí ilé isẹ́ ọlọ́pàá
Látìgbà náà, kọmísánà ọlọ́pàá, Rabiu Yusuf ti rán ikọ̀ òsìsẹ́ àti ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ alágbára lọ síbẹ̀ láti bojú tó agbègbè náà kí ọwọ́ lè tẹ àwọn ọ̀daràn, kí wọ́n sì dá ẹni tó wà nígbèkùn sílẹ̀.
Ilé isẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kano sọ pé, kí ẹnikẹ́ni tó bá ní ìròyìn nípa wọn, kàn sí ilé isẹ́ ọlọ́pàá tó bá wà ní tòsí wọn.












