Akẹkọbinrin 111 lo sọnu ni Yobe

Oríṣun àwòrán, Ijọba ipinlẹ Yobe
Komisana ọlọpa nipinlẹ Yobe, Abdulmaliki Sunmọnu sọ wipe akẹkọbirin mọkanlelaadọfa lo sọnu l'abule Dapchi lẹyin ikọlu Boko Haram.
Nigba ton bawọn akọroyin sọrọ lọjọru, Ọgbẹni Sunmọnu sọ wipe akẹkọbirin ọgọrun mẹjọlenimẹdogun ninu awọn ọgarun mẹsan ati ogunlelọkan.
Ọga ọlọpa naa sọ wipe wọn ti ri awọn kan ninu awọn akẹkọbirin naa, eyi to tumọ si wipe iye awọn akẹkọbirin to sọnu ti dinku ni mọkanlalaadọfa
Ijọba ipinle Yobe ti kọkọ f'idi ọrọ mule fun ileesẹ BBC pe o le ni aadota akẹkọobirin ile ẹko naa ti wọn nwa lẹyin ikọlu afurasi Boko Haram nilu Dapchi.
Awọn agbebọn yabo ilu naa nirọlẹ ọjọ aje, wọn si wọ inu ọgba ileewe girama awọn akẹkọbinrin naa. Nigba ti wọn o fi de ibẹ, pupọ ninu awọn akẹkọ ati olukọ ti fẹsẹ fẹ.
Awọn tiṣẹlẹ naa s'oju wọn, ti wọn si gbọ iro ibọn ati ibugbamu ni, awọn agbebọn naa wọ ilu Dapchi pẹlu ọkọ to le ni mejila.
Ounjẹ lawọn Boko Haram naa wa wa, ki wọn to jọmọ gbe
Bi wọn ṣe sunmọ ileewe naa ni pupọ ninu awọn akẹkọ ati olukọ sa wọ inu igbo to wa nitosi, sugbọn titi di ana, aadọrun eeyan ni wọn ko tii ri.
Awọn araalu to n gbe lẹba ileewe naa sọ fun BBC pe, awọn eeyan miiran to to ilaji awọn eeyan ti wọn nwa, ni wọn ri nibi ti wọn fi ara pamọ si lawọn abule to wa nitosi.
Awọn alaṣẹ ijọba ni awọn ṣi n gbiyanju lati ṣawari awọn ọmọbinrin to ku.

Oríṣun àwòrán, Ijọba ipinlẹ Yobe
Ọkan lara awọn olukọ to pade awọn agbebọn naa lẹnu iloro ileewe naa ni, ounjẹ ni wọn wa wa,
ko to di wipe wọn gbẹyin lọ ja ileewe naa lole ati awọn ile itaja kan ninu ilu naa eyi to waye fun wakati mẹta.
Iru iṣẹlẹ yi ni tawọn akẹkọbinrin 276 ti wọn ji gbe ni ileewe kan ni Chibok lọdun 2014, eyi to mi gbogbo agbaye titi.
Awọn akẹkọbinrin Chibok ọhun to le ni ọgọrun lo ṣi wa ni ahamọ Boko Haram.












