Àwọn agbébọn jí alága ẹgbẹ́ òsèlú PDP gbé ní Kogi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn agbebon tí wón wo aṣọ ọmọ iṣẹ́ ológun ni a gbọ́ pé, wón ti jí alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tí ìjọba ìbílè Okene, Ogbeni Musa Adelabu, gbé lọ ni dédé agogo kan òru ọjọ́ ìsimi.Nígbà tí ó ń fi ọ̀rọ̀ náà lédè, alága ẹgbẹ́ òṣèlú náà ni ìpínlè Kogi, Sam Uhuotu, sọ wí pé, Ìpínlẹ̀ Kogi, tí di ẹru jeje fún olùgbé ìpínlè náà.
Ó te siwaju pé, àwọn agbebon náà wo aṣọ ológun nígbà tí ṣe akọlù sí ilé ẹ rè ni dédé aago kan òru ọjọ́ ìsimiÓ fi kun pé, akọlù sí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlè náà fẹ́ àbójútó látàrí bíi àwọn agbebon tí wón ń wọṣọ ológun láti ṣe irú ìṣe láabi náà ń wọ́pọ̀ sii.Uhuotu ṣàlàyé wí pé, títí di àsìkò tí a ń sọ̀rọ̀ yìí, kò sí eni tí ó mọ, ibi tí alága náà wọlé sí.Àmọ́ ṣáá o, alukoro àjọ olopaa ní ìpínlè náà, Williams Aya, sọ wí pé, kò tí ì sí eni tí ó mú ẹ̀sùn íjini gbé bẹ́ẹ̀ tó wọn létí.










